bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Titus 2
Titus 2
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 3 →
1
ṢUGBỌN iwọ mã sọ ohun ti o yẹ si ẹkọ́ ti o yè kõro:
2
Ki awọn àgba ọkunrin jẹ ẹni iwọntunwọnsin, ẹni-ọ̀wọ, alairekọja, ẹniti o yè kõro ni igbagbọ́, ni ifẹ, ni sũru.
3
Bẹ̃ gẹgẹ ni ki awọn agba obinrin jẹ ẹni-ọ̀wọ ni iwa, ki nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin, tabi ọmuti, bikoṣe olukọni ni ohun rere;
4
Ki nwọn ki o le tọ́ awọn ọdọmọbirin lati fẹran awọn ọkọ wọn, lati fẹran awọn ọmọ wọn,
5
Lati jẹ alairekọja, mimọ́, òṣiṣẹ́ nile, ẹni rere, awọn ti ntẹriba fun awọn ọkọ wọn, ki ọrọ Ọlọrun ki o máṣe di isọ̀rọ-òdi si.
6
Bẹ̃ gẹgẹ ni ki o gbà awọn ọdọmọkunrin niyanju lati jẹ alairekọja.
7
Ninu ohun gbogbo mã fi ara rẹ hàn li apẹrẹ iṣẹ rere: ninu ẹkọ́ mã fi aiṣebajẹ hàn, ìwa àgba,
8
Ọ̀rọ ti o yè kõro, ti a kò le da lẹbi; ki oju ki o tì ẹniti o nṣòdi, li aini ohun buburu kan lati wi si wa.
9
Gbà awọn ọmọ-ọdọ niyanju lati mã tẹriba fun awọn oluwa wọn, ki nwọn ki o mã ṣe ohun ti o wu wọn ninu ohun gbogbo; ki nwọn ki o má gbó wọn lohùn;
10
Ki nwọn ki o máṣe irẹjẹ, ṣugbọn ki nwọn ki o mã fi iwa otitọ rere gbogbo han; ki nwọn ki o le mã ṣe ẹkọ́ Ọlọrun Olugbala wa li ọṣọ́ ninu ohun gbogbo.
11
Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan,
12
O nkọ́ wa pe, ki a sẹ́ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mã wà li airekọja, li ododo, ati ni ìwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi;
13
Ki a mã wo ọna fun ireti ti o ni ibukún ati ifarahan ogo Ọlọrun wa ti o tobi, ati ti Olugbala wa Jesu Kristi;
14
Ẹniti o fi ara rẹ̀ fun wa, ki on ki o le rà wa pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ gbogbo, ki o si le wẹ awọn enia kan mọ́ fun ara rẹ̀ fun ini on tíkararẹ awọn onitara iṣẹ rere.
15
Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o mã sọ, ki o si ma gbà-ni-niyanju, ki o si mã fi aṣẹ gbogbo ba-ni-wi. Máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o gàn ọ.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3