bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Zephaniah 2
Zephaniah 2
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 3 →
1
Ẹ kó ara nyin jọ pọ̀, ani, ẹ kójọ pọ̀ orilẹ-ède ti kò nani;
2
Ki a to pa aṣẹ na, ki ọjọ na to kọja bi iyàngbò, ki gbigboná ibinu Oluwa to de ba nyin, ki ọjọ ibinu Oluwa ki o to de ba nyin.
3
Ẹ wá Oluwa, gbogbo ẹnyin ọlọkàn tutù aiye, ti nṣe idajọ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwa-pẹ̀lẹ: boya a o pa nyin mọ li ọjọ ibinu Oluwa.
4
Nitoripe a o kọ̀ Gasa silẹ, Aṣkeloni yio si dahoro: nwọn o le Aṣdodu jade li ọsangangan, a o si fà Ekronu tu kuro.
5
Egbe ni fun awọn ẹniti ngbe agbègbe okun, orilẹ-ède awọn ara Kereti! ọ̀rọ Oluwa dojukọ nyin; iwọ Kenaani, ilẹ awọn ara Filistia, emi o tilẹ pa ọ run, ti ẹnikan kì yio gbe ibẹ̀ mọ.
6
Agbègbe okun yio si jẹ ibujoko ati agọ fun awọn olùṣọ agùtan, ati agbo fun agbo-ẹran.
7
Agbègbe na yio si wà fun iyokù ile Juda; nwọn o jẹ̀ li ori wọn: ni ile Aṣkeloni wọnni ni nwọn o dùbulẹ li aṣãlẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ̀ wọn wò, yio si yi igbèkun wọn padà kuro.
8
Emi ti gbọ́ ẹgàn Moabu, ati ẹlẹyà awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti kẹgàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbe ara wọn ga si agbègbe wọn.
9
Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ọlọrun Israeli, Dajudaju Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni bi Gomorra, bi titàn wèrepe, ati bi ihò iyọ, ati ìdahoro titi lai, iyokù awọn enia mi o kó wọn, iyokù awọn orilẹ-ède mi yio si jogun wọn.
10
Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoripe nwọn ti kẹgàn, nwọn si ti gbe ara wọn ga si enia Oluwa awọn ọmọ-ogun.
11
Oluwa yio jẹ ibẹ̀ru fun wọn: nitori on o mu ki gbogbo òriṣa ilẹ aiye ki o rù; enia yio si ma sìn i, olukuluku lati ipò rẹ̀ wá, ani gbogbo erekùṣu awọn keferi.
12
Ẹnyin ara Etiopia pẹlu, a o fi idà mi pa nyin.
13
On o si nà ọwọ́ rẹ̀ si ihà ariwa, yio si pa Assiria run; yio si sọ Ninefe di ahoro, ati di gbigbẹ bi aginjù.
14
Agbo-ẹran yio si dùbulẹ li ãrin rẹ̀, gbogbo ẹranko awọn orilẹ-ède: ati ẹiyẹ òfu ati õrẹ̀ yio ma gbe atẹrigbà rẹ̀, ohùn wọn yio kọrin li oju fèrese; idahoro yio wà ninu iloro: nitoriti on o ṣi iṣẹ kedari silẹ.
15
Eyi ni ilu alayọ̀ na ti o ti joko lainani ti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ni, kò si si ẹnikan ti mbẹ lẹhìn mi: on ha ti ṣe di ahoro bayi, ibùgbe fun ẹranko lati dubulẹ si! olukuluku ẹniti o ba kọja lọdọ rẹ̀ yio pòṣe yio si mì ọwọ́ rẹ̀.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3