bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
2 Chronicles 13
2 Chronicles 13
Yoruba 2010
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 14 →
1
Ní ọdún kejidinlogun ìjọba Jeroboamu ni Abija jọba ní ilẹ̀ Juda.
2
Ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Mikaya, ọmọ Urieli ará Gibea. Nígbà kan, ogun bẹ́ sílẹ̀ láàrin Abija ati Jeroboamu.
3
Abija kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) akọni ọmọ ogun jọ láti bá Jeroboamu jagun. Jeroboamu náà kó ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) akọni ọmọ ogun jọ.
4
Abija gun orí òkè Semaraimu tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu lọ. Ó kígbe lóhùn rara, ó ní: “Gbọ́ mi, ìwọ Jeroboamu ati gbogbo ẹ̀yin eniyan Israẹli,
5
ṣé ẹ ẹ̀ mọ̀ pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ti fi iyọ̀ bá Dafidi dá majẹmu ayérayé pé àtìrandíran rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí Israẹli títí lae?
6
Sibẹsibẹ, Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi, dìde, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Solomoni, oluwa rẹ̀.
7
Ó sì lọ kó àwọn jàǹdùkú ati àwọn aláìníláárí eniyan kan jọ, wọ́n pe Rehoboamu ọmọ Solomoni níjà. Rehoboamu jẹ́ ọmọde nígbà náà, kò sì ní ìrírí tó láti dojú ìjà kọ wọ́n.
8
Nisinsinyii, ẹ rò pé ẹ lè dojú ìjà kọ ìjọba OLUWA, tí ó gbé lé àwọn ọmọ Dafidi lọ́wọ́; nítorí pé ẹ pọ̀ ní iye ati pé ẹ ní ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù tí Jeroboamu fi wúrà ṣe tí ó pè ní ọlọrun yín?
9
Ẹ ti lé àwọn alufaa OLUWA kúrò lọ́dọ̀ yín: àwọn ọmọ Aaroni, ati àwọn ọmọ Lefi. Ẹ yan alufaa mìíràn dípò wọn bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá ti mú akọ mààlúù tabi aguntan meje wá, ẹ̀ ń yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ alufaa àwọn oriṣa tí kì í ṣe Ọlọrun.
10
“Ṣugbọn ní tiwa, OLUWA Ọlọrun ni à ń sìn; a kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ọmọ Aaroni ni àwọn alufaa wa, àwọn ọmọ Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
11
Ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́ ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun, tí wọ́n sì ń sun turari. Wọ́n ń fi àkàrà ìfihàn sórí tabili wúrà. Ní alaalẹ́, wọ́n ń tan fìtílà wúrà lórí ọ̀pá fìtílà rẹ̀; nítorí àwa ń ṣe ohun tí Ọlọrun wa pa láṣẹ fún wa, ṣugbọn ẹ̀yin ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
12
Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.”
13
Ṣugbọn Jeroboamu ti rán ọ̀wọ́ ọmọ ogun kan lọ láti kọlu àwọn ọmọ ogun Juda látẹ̀yìn. Àwọn ọmọ ogun Jeroboamu wà níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, àwọn tí ó rán tí wọ́n sápamọ́ sì wà lẹ́yìn wọn.
14
Nígbà tí Juda rí i pé ogun wà níwájú ati lẹ́yìn wọn, wọ́n ké pe OLUWA, àwọn alufaa sì fọn fèrè ogun.
15
Àwọn ọmọ ogun Juda hó ìhó ogun, bí wọ́n sì ti kígbe ni Ọlọrun ṣẹgun Jeroboamu ati àwọn ọmọ ogun Israẹli fún Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda.
16
Àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá níwájú àwọn ọmọ ogun Juda, Ọlọrun sì fi wọ́n lé àwọn ọmọ ogun Juda lọ́wọ́.
17
Abija ati àwọn ọmọ ogun Juda pa àwọn ọmọ ogun Israẹli ní ìpakúpa, tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ mẹẹdọgbọn (500,000) fi kú ninu àwọn akọni ọmọ ogun Israẹli.
18
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda ṣe tẹ orí àwọn ọmọ Israẹli ba tí wọ́n sì ṣẹgun wọn, nítorí pé àwọn ọmọ Juda gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.
19
Abija lé Jeroboamu, ó sì gba ìlú Bẹtẹli, ati Jeṣana, ati Efuroni ati àwọn ìletò tí ó yí wọn ká lọ́wọ́ rẹ̀.
20
Jeroboamu kò sì lè gbérí ní àkókò Abija. Nígbà tí ó yá Ọlọrun lu Jeroboamu pa.
21
Ṣugbọn agbára Abija bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ síi. Iyawo mẹrinla ni ó ní; ó sì bí ọmọkunrin mejilelogun ati ọmọbinrin mẹrindinlogun.
22
Gbogbo nǹkan yòókù ti Abija ṣe ní àkókò ìjọba rẹ̀, ati ohun tí ó sọ, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn wolii Ido.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36