bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
2 Chronicles 19
2 Chronicles 19
Yoruba 2010
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 20 →
1
Jehoṣafati ọba Juda pada ní alaafia sí ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
2
Ṣugbọn Jehu, aríran, ọmọ Hanani lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ṣé ó dára kí o máa ran eniyan burúkú lọ́wọ́, kí o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra OLUWA? Nítorí èyí, ibinu OLUWA ru sí ọ.
3
Sibẹsibẹ àwọn nǹkankan wà tí o ṣe tí ó dára, o run àwọn ère oriṣa Aṣera ní ilẹ̀ yìí, o sì ti ṣe ọkàn rẹ gírí láti tẹ̀lé Ọlọ́run.”
4
Jerusalẹmu ni Jehoṣafati ń gbé, ṣugbọn a máa lọ jákèjádò ilẹ̀ náà láàrin àwọn ọmọ Israẹli, láti Beeriṣeba títí dé agbègbè olókè Efuraimu, a máa káàkiri láti yí wọn lọ́kàn pada sí OLUWA Ọlọrun baba wọn.
5
Ó yan àwọn adájọ́ ní gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda.
6
Ó kìlọ̀ fún wọn ó ní, “Ẹ ṣọ́ra gan-an, nítorí pé kì í ṣe eniyan ni ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún, OLUWA ni. Ẹ sì ranti pé OLUWA wà lọ́dọ̀ yín bí ẹ ti ń ṣe ìdájọ́.
7
Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì ṣọ́ra pẹlu àwọn nǹkan tí ẹ ó máa ṣe, nítorí pé OLUWA Ọlọrun wa kì í yí ìdájọ́ po, kì í ṣe ojuṣaaju, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”
8
Jehoṣafati tún yan àwọn kan ní Jerusalẹmu ninu àwọn ọmọ Lefi, ati àwọn alufaa ati àwọn baálé baálé ní Israẹli, láti máa fi òfin OLUWA ṣe ìdájọ́ ati láti máa yanjú ẹjọ́ tí kò bá di àríyànjiyàn.
9
Ó kìlọ̀ fún wọn, ó ní “Ohun tí ẹ gbọdọ̀ máa fi tọkàntọkàn ṣe, pẹlu ìbẹ̀rù OLUWA ati òtítọ́ nìyí:
10
Nígbàkúùgbà tí àwọn arakunrin yín bá mú ẹjọ́ wá siwaju yín láti ìlú kan, kì báà ṣe ti ìtàjẹ̀sílẹ̀, tabi ti nǹkan tí ó jẹ mọ́ òfin, tabi àṣẹ, tabi ìlànà, ẹ níláti ṣe àlàyé fún wọn kí wọ́n má baà jẹ̀bi níwájú OLUWA, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí ẹ̀yin náà ati àwọn arakunrin yín. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ gbọdọ̀ máa ṣe kí ẹ má baà jẹ̀bi.
11
Amaraya, olórí alufaa ni alabojuto yín ninu gbogbo nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ OLUWA. Sebadaya, ọmọ Iṣimaeli, tí ó jẹ́ gomina ní Juda ni alabojuto lórí ọ̀rọ̀ ìlú, àwọn ọmọ Lefi yóo sì máa ṣe òjíṣẹ́ yín. Ẹ má bẹ̀rù. Kí OLUWA wà pẹlu ẹ̀yin tí ẹ dúró ṣinṣin.”
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 20 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36