bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
2 Corinthians 4
2 Corinthians 4
Yoruba 2010
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 5 →
1
Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì.
2
A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere.
3
Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí.
4
Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun.
5
Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi.
6
Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.
7
Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa.
8
A ní oríṣìíríṣìí ìṣòro, ṣugbọn wọn kò wó wa mọ́lẹ̀; ọkàn wa ń dààmú, ṣugbọn a kò ṣe aláìní ìrètí.
9
Àwọn eniyan ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn Ọlọrun kò fi wá sílẹ̀. Wọ́n gbé wa ṣubú, ṣugbọn wọn kò lè pa wá.
10
À ń ru ikú Jesu káàkiri lára wa nígbà gbogbo, kí ìyè Jesu lè hàn lára wa.
11
Nítorí pé nígbà gbogbo ni à ń fi ẹ̀mí wa wéwu nítorí Jesu, níwọ̀n ìgbà tí a wà láàyè, kí ìyè Jesu lè hàn ninu ẹran-ara wa tí yóo di òkú.
12
Ó wá jẹ́ pé ikú ní ń ṣiṣẹ́ ninu wa, nígbà tí ìyè ń ṣiṣẹ́ ninu yín.
13
Àkọsílẹ̀ kan sọ pé, “Mo gbàgbọ́, nítorí náà ni mo fi sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó ti jẹ́ pé a ní ẹ̀mí igbagbọ kan náà, àwa náà gbàgbọ́, nítorí náà ni a fi ń sọ̀rọ̀.
14
A mọ̀ pé ẹni tí ó jí Oluwa Jesu dìde yóo jí àwa náà dìde pẹlu Jesu, yóo wá mú àwa ati ẹ̀yin wá sí iwájú rẹ̀.
15
Nítorí tiyín ni gbogbo èyí, kí oore-ọ̀fẹ́ lè máa pọ̀ sí i fún ọpọlọpọ eniyan, kí ọpẹ́ yín lè máa pọ̀ sí i fún ògo Ọlọrun.
16
Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ.
17
Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ.
18
Kì í ṣe àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí ni a tẹjúmọ́, bíkòṣe àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí. Nítorí àwọn nǹkan tí yóo wà fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí. Àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí ni yóo wà títí laelae.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13