bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
2 Corinthians 6
2 Corinthians 6
Yoruba 2010
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 7 →
1
Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí gbígbà tí ẹ gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jẹ́ lásán.
2
Nítorí Ọlọrun sọ pé, “Mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ nígbà tí o bá ojurere mi pàdé; mo ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà.” Ìsinsìnyìí ni àkókò ojurere Ọlọrun. Òní ni ọjọ́ ìgbàlà.
3
A kò fi ohun ìkọsẹ̀ kankan siwaju ẹnikẹ́ni, kí àwọn eniyan má baà rí wí sí iṣẹ́ wa.
4
Ṣugbọn ninu gbogbo nǹkan, à ń fi ara wa sípò àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Ọlọrun. A ti fara da ọpọlọpọ nǹkan ní àkókò inúnibíni, ninu ìdààmú, ati ninu ìṣòro;
5
nígbà tí wọ́n nà wá ati nígbà tí a wà lẹ́wọ̀n, ní àkókò ìrúkèrúdò ati ní àkókò tí iṣẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn, tí à ń pa ebi mọ́nú.
6
À ń ṣiṣẹ́ pẹlu ọkàn kan; pẹlu ọgbọ́n ati sùúrù, pẹlu inú rere ati ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, pẹlu ìfẹ́ tí kò lẹ́tàn.
7
À ń ṣe iṣẹ́ wa pẹlu òtítọ́ inú ati agbára Ọlọrun. A mú ohun ìjà òdodo lọ́wọ́ ọ̀tún ati lọ́wọ́ òsì.
8
Bí a ti ń gba ọlá, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìtìjú. Bí a ti ń gba èébú, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìyìn. Àwọn ẹlòmíràn kà wá sí ẹlẹ́tàn, bẹ́ẹ̀ sì ni olóòótọ́ ni wá.
9
Ìwà wa kò yé àwọn eniyan, sibẹ gbogbo eniyan ni ó mọ̀ wá. A dàbí ẹni tí ń kú lọ, sibẹ a tún wà láàyè. A ti ní ìrírí ìtọ́ni pẹlu ìjìyà, sibẹ ìjìyà yìí kò pa wá.
10
A ní ìrírí ìbànújẹ́ nígbà gbogbo, sibẹ à ń yọ̀. A jẹ́ aláìní, sibẹ a ti sọ ọpọlọpọ di ọlọ́rọ̀. A dàbí àwọn tí kò ní nǹkankan, sibẹ a ní ohun gbogbo.
11
A ti sọ òtítọ́ inú wa fun yín, ẹ̀yin ará Kọrinti. Ọkàn wa ṣípayá si yín.
12
Kò sí ohun kan ní ọkàn wa si yín. Bí ohun kan bá wà, a jẹ́ pé ní ọkàn tiyín ni.
13
Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ. Ohun tí ó yẹ yín ni pé kí ẹ ṣí ọkàn yín payá sí wa.
14
Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀?
15
Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀?
16
Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé, “N óo máa gbé ààrin wọn, n óo máa káàkiri ní ààrin wọn. N óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.
17
Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí. Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́, kí n lè gbà yín.
18
N óo jẹ́ baba fun yín, ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi, lọkunrin ati lobinrin yín. Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13