bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Hebrews 3
Hebrews 3
Yoruba 2010
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 4 →
1
Nítorí náà, ẹ̀yin ará ninu Oluwa, tí a jọ ní ìpín ninu ìpè tí ó ti ọ̀run wá, ẹ ṣe akiyesi Jesu, tíí ṣe òjíṣẹ́ ati Olórí Alufaa ìjẹ́wọ́ igbagbọ wa.
2
Ẹ rí i pé ó ṣe olóòótọ́ sí Ọlọrun tí ó yàn án gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣe oloòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun.
3
Nítorí bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti ní ọlá ju ilé tí ó kọ́ lọ, bẹ́ẹ̀ ni Jesu yìí ní ọlá ju Mose lọ.
4
Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo.
5
Mose ṣe olóòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ. A rán an láti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun yóo fi fún un láti sọ ni.
6
Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa.
7
Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8
ẹ má ṣe agídí, gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ìṣọ̀tẹ̀, ní àkókò ìdánwò ninu aṣálẹ̀,
9
nígbà tí àwọn baba-ńlá yín dán mi wò, tí wọ́n fi rí iṣẹ́ mi fún ogoji ọdún.
10
Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn. Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn. Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’
11
Ni mo bá búra pẹlu ibinu, pé wọn kò ní dé ibi ìsinmi mi.”
12
Ẹ kíyèsára, ará, kí ó má ṣe sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí yóo ní inú burúkú tóbẹ́ẹ̀ ti kò ní ní igbagbọ, tí yóo wá pada kúrò lẹ́yìn Ọlọrun alààyè.
13
Ṣugbọn ẹ máa gba ara yín níyànjú lojoojumọ níwọ̀n ìgbà tí ọ̀rọ̀ “Òní” tí Ìwé Mímọ́ sọ bá ti bá àwa náà wí, kí ẹ̀ṣẹ̀ má baà tan ẹnikẹ́ni lọ, kí ó sì mú kí ó ṣe agídí sí Ọlọrun.
14
Nítorí a ti di àwọn tí ó ń bá Kristi kẹ́gbẹ́ bí a bá fi ọkàn tán an títí dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti fi ọkàn tán an ní ìbẹ̀rẹ̀ igbagbọ wa.
15
Bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe agídí gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ọ̀tẹ̀.”
16
Mò ń bèèrè, àwọn ta ni ó gbọ́ tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀? Ṣebí gbogbo àwọn tí wọ́n bá Mose jáde kúrò ní Ijipti ni.
17
Àwọn ta ni Ọlọrun bínú sí ní ogoji ọdún? Ṣebí àwọn tí ó ṣẹ̀ ni, tí òkú wọn wà káàkiri ní aṣálẹ̀.
18
Àwọn ta ni ó búra pé wọn kò ní wọ inú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn aláìgbọràn ni.
19
A rí i pé wọn kò lè wọ inú ìsinmi yìí nítorí wọn kò gbàgbọ́.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
Recommended Reading
Commentary
Hebrews Commentaries
→
Devotional
Hebrews Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba Study Bible
→