bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Hebrews 5
Hebrews 5
Yoruba 2010
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 6 →
1
Nítorí ẹnikẹ́ni tí a bá yàn láàrin àwọn eniyan láti jẹ́ olórí alufaa, a yàn án bí aṣojú àwọn eniyan níwájú Ọlọrun, kí ó lè máa mú àwọn ọrẹ ati ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá siwaju Ọlọrun.
2
Ó lè fi sùúrù bá àwọn tí wọ́n ṣìnà nítorí wọn kò gbọ́ lò, nítorí pé eniyan aláìlera ni òun náà.
3
Nítorí èyí, bí ó ti ń rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti òun alára.
4
Kò sí ẹni tíí yan ara rẹ̀ sí ipò yìí. Ṣugbọn àwọn tí Ọlọrun bá pè ni à ń yàn, bíi Aaroni.
5
Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Kristi náà kò yan ògo yìí fúnrarẹ̀, láti jẹ́ olórí alufaa. Ọlọrun ni ó yàn án. Ọlọrun ni ó sọ fún un pé, “Ìwọ ni Ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.”
6
Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ ní ibòmíràn pé, “Alufaa ni ọ́ títí laelae gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”
7
Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà.
8
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ.
9
Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́.
10
Òun ni Ọlọrun pè ní olórí alufaa gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.
11
A ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ fun yín nípa Mẹlikisẹdẹki yìí. Ọ̀rọ̀ náà ṣòro láti túmọ̀ nígbà tí ọkàn yín ti le báyìí.
12
Nítorí ó ti yẹ kí ẹ di olùkọ́ni ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Sibẹ ẹ tún wà ninu àwọn tí a óo máa kọ́ ní “A, B, D,” nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun. Ẹ wà ninu àwọn tí a óo máa fi wàrà bọ́, ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi.
13
Nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá sì ń mu wàrà, kò tíì mọ ẹ̀kọ́ nípa òdodo, nítorí ọmọ-ọwọ́ ni irú wọn.
14
Ṣugbọn oúnjẹ gidi ni àgbàlagbà máa ń jẹ, àwọn tí ìrírí wọn fún ọjọ́ pípẹ́ ti fún ní òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin nǹkan rere ati nǹkan burúkú.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13