bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Hosea 12
Hosea 12
Yoruba 2010
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 13 →
1
“Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.”
2
OLUWA ní ẹjọ́ tí yóo bá àwọn ọmọ Juda rò, yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn, yóo sì san ẹ̀san iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn.
3
Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì.
4
Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀.
5
OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀:
6
Nítorí náà, ẹ yipada nípa agbára Ọlọrun yín, ẹ di ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo mú, kí ẹ sì dúró de Ọlọrun yín nígbà gbogbo.
7
OLUWA ní, “Efuraimu jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé òṣùnwọ̀n èké lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn láti máa ni eniyan lára.
8
Efuraimu ní, ‘Mo ní ọrọ̀, mo ti kó ọrọ̀ jọ fún ara mi, ṣugbọn gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ kò lè mú ẹ̀bi rẹ̀ kúrò.’
9
Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ láti ilẹ̀ Ijipti; n óo tún mú ọ pada gbé inú àgọ́, bí àwọn ọjọ́ àjọ ìyàsọ́tọ̀.
10
“Mo bá àwọn wolii sọ̀rọ̀; èmi ni mo fi ọpọlọpọ ìran hàn wọ́n, tí mo sì tipasẹ̀ wọn pa ọpọlọpọ òwe.
11
Ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà wà ní Gileadi, dájúdájú yóo parun; bí wọ́n bá fi akọ mààlúù rúbọ ní Giligali, pẹpẹ wọn yóo dàbí òkúta tí a kójọ ní poro oko.”
12
Jakọbu sálọ sí ilẹ̀ Aramu, níbẹ̀ ni ó ti singbà, tí ó ṣiṣẹ́ darandaran, nítorí iyawo tí ó fẹ́.
13
Nípasẹ̀ wolii kan ni OLUWA ti mú Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, nípasẹ̀ wolii kan ni a sì ti pa á mọ́.
14
Efuraimu ti mú èmi, OLUWA rẹ̀ bínú lọpọlọpọ, nítorí náà, n óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lé e lórí, òun tí ó gàn mí ni yóo di ẹni ẹ̀gàn.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14