bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Hosea 14
Hosea 14
Yoruba 2010
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
1
Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
2
Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo.
3
Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.”
4
Ọlọrun ní, “N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn, n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn, nítorí n kò bínú sí wọn mọ́.
5
Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli, ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì, gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni.
6
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀; ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi, òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni.
7
Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi, wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà; wọn óo sì tanná bí àjàrà, òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni.
8
Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’ Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀, tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀. Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn. Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.”
9
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14