bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Leviticus 3
Leviticus 3
Yoruba 2010
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 4 →
1
“Bí ẹnìkan bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia, tí ó sì mú ẹran láti inú agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ náà, kì báà jẹ́ akọ tabi abo, ó níláti jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n níwájú OLUWA.
2
Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹran náà, kí ó sì pa á lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí àwọn alufaa ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo.
3
Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,
4
ati kíndìnrín rẹ̀ mejeeji pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n. Nígbà tí ó bá ń yọ kíndìnrín rẹ̀, yóo yọ ẹ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́ ọn láti fi rú ẹbọ sísun sí OLUWA.
5
Àwọn ọmọ Aaroni yóo sun wọ́n lórí igi tí ó wà ninu iná lórí pẹpẹ; ẹbọ sísun ni, tí ó ní òórùn dídùn, tí inú OLUWA sì dùn sí.
6
“Bí ó bá jẹ́ pé aguntan tabi ewúrẹ́ ni yóo mú láti inú agbo ẹran rẹ̀ láti fi rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, kì báà jẹ́ akọ tabi abo ẹran, ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n.
7
Bí ó bá jẹ́ ọ̀dọ́ aguntan ni yóo fi rúbọ, kí ó mú un wá siwaju OLUWA,
8
kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; kí àwọn ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà yípo.
9
Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá rẹ̀, gbogbo ọ̀rá tí ó wà ní ìrù rẹ̀ títí dé ibi egungun ẹ̀yìn rẹ̀, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo gbogbo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,
10
kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, ati ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí ati gbogbo ẹ̀dọ̀ rẹ̀.
11
Alufaa yóo sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi iná sun sí OLUWA.
12
“Bí ó bá jẹ́ pé ewúrẹ́ ni yóo fi rú ẹbọ náà, kí ó mú un wá siwaju OLUWA,
13
kí ó gbé ọwọ́ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú Àgọ́ Àjọ náà; àwọn ọmọ Aaroni yóo sì da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo.
14
Yóo sì yọ àwọn nǹkan wọnyi ninu rẹ̀ láti fi rú ẹbọ tí a fi iná sun sí OLUWA: gbogbo ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ọ̀rá tí ó bo ìfun rẹ̀,
15
kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀.
16
Kí alufaa sun wọ́n lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn. Ti OLUWA ni gbogbo ọ̀rá ẹran.
17
Kí èyí jẹ́ ìlànà ayérayé fún àtìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín, pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tabi ẹ̀jẹ̀.”
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27