bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Leviticus 9
Leviticus 9
Yoruba 2010
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 10 →
1
Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati àwọn àgbààgbà Israẹli;
2
ó wí fún Aaroni pé, “Mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati àgbò kan fún ẹbọ sísun kí o sì fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA. Àwọn ẹran mejeeji yìí kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.
3
Sì sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ọmọ mààlúù kan ati ọ̀dọ́ aguntan kan fún ẹbọ sísun, kí àwọn mejeeji jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì gbọdọ̀ ní àbààwọ́n.
4
Sì mú akọ mààlúù kan ati àgbò kan fún ẹbọ alaafia, kí ẹ fi wọ́n rúbọ níwájú OLUWA pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò, nítorí pé OLUWA yóo fi ara hàn yín lónìí.’ ”
5
Wọ́n mú àwọn ohun tí Mose paláṣẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ, gbogbo ìjọ eniyan sì dúró níwájú OLUWA.
6
Mose sọ fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA paláṣẹ fun yín láti ṣe nìyí, ògo OLUWA yóo hàn sí yín.”
7
Lẹ́yìn náà, Mose sọ fún Aaroni pé, “Súnmọ́ ibi pẹpẹ, kí o sì rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ati ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ ati fún àwọn eniyan náà. Gbé ẹbọ àwọn eniyan náà wá, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”
8
Aaroni bá súnmọ́ ibi pẹpẹ náà, ó pa ọ̀dọ́ mààlúù fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀.
9
Àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá fún un, ó sì ti ìka bọ̀ ọ́, ó fi kan ara ìwo pẹpẹ, ó sì da ẹ̀jẹ̀ yòókù sí ìdí pẹpẹ.
10
Ó mú ọ̀rá ọ̀dọ́ mààlúù náà, ati àwọn kíndìnrín rẹ̀ ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀ kúrò ninu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sun wọ́n lórí pẹpẹ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
11
Ó sì dáná sun ẹran ati awọ mààlúù náà lẹ́yìn ibùdó.
12
Ó pa ẹran ẹbọ sísun, àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì dà á sí ara pẹpẹ yípo.
13
Wọ́n gbé ẹran ẹbọ sísun tí wọ́n ti gé sí wẹ́wẹ́, ati orí rẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, ó sì sun wọ́n lórí pẹpẹ.
14
Ó fọ àwọn nǹkan inú rẹ̀, ati ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun wọ́n papọ̀ pẹlu ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.
15
Lẹ́yìn náà ó fa ẹran ẹbọ sísun àwọn eniyan náà kalẹ̀, ó mú ewúrẹ́ ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan náà, ó pa á, ó sì fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ti àkọ́kọ́.
16
Ó gbé ẹran ẹbọ sísun wá, ó sì fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
17
Ó gbé ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan ninu rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀.
18
Ó pa akọ mààlúù ati àgbò ẹbọ alaafia fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ rẹ̀ gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì dà á sórí pẹpẹ náà yípo.
19
Ó mú ọ̀rá akọ mààlúù, ati ti àgbò náà, pẹlu ìrù wọn tí ó lọ́ràá, ati ọ̀rá tí ó bo àwọn nǹkan inú wọn, ati kíndìnrín ati ẹ̀dọ̀ wọn.
20
Ó kó gbogbo ọ̀rá náà lé orí igẹ̀ ẹran náà; ó sun ún lórí pẹpẹ.
21
Ṣugbọn ó mú àwọn igẹ̀ ẹran náà ati itan ọ̀tún wọn, ó fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, bí Mose ti pa á láṣẹ.
22
Lẹ́yìn náà, Aaroni kọjú sí àwọn eniyan náà, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn náà, ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi tí ó ti ń rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia.
23
Mose ati Aaroni bá wọ inú Àgọ́ Àjọ lọ. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn eniyan náà, ògo OLUWA sì yọ sí gbogbo wọn.
24
Lójijì, iná ṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ OLUWA wá, ó jó ẹbọ sísun náà, ati ọ̀rá tí ó wà lórí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n kígbe sókè, wọ́n sì dojúbolẹ̀.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27