bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Romans 12
Romans 12
Yoruba 2010
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 13 →
1
Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ̀yin ará, mo fỌlọrun aláàánú bẹ̀ yín pé kí ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ bí ẹbọ mímọ́ tí ó yẹ láti fi sin Ọlọrun. Èyí ni iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ yín.
2
Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé.
3
Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un.
4
Nítorí bí a ti ní ẹ̀yà ara pupọ ninu ara kan, tí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara wọnyi kì í sìí ṣe iṣẹ́ kan náà,
5
bẹ́ẹ̀ gan-an ni gbogbo wa, bí á tilẹ̀ pọ̀, ara kan ni wá ninu Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ ẹ̀yà ara ẹnìkejì rẹ̀.
6
Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ.
7
Bí ó bá jẹ́ ẹ̀bùn láti darí ètò ni, kí á lò ó láti darí ètò. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn ìkọ́ni, kí ó lo ẹ̀bùn rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.
8
Bí ó bá ní ẹ̀bùn láti fúnni ní ọ̀rọ̀ ìwúrí, kí ó lò ó láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì jìnnà. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, kí ó ṣe é pẹlu ọkàn kan. Ẹni tí ó bá ní ẹ̀bùn láti ṣe aṣiwaju, kí ó ṣe é tọkàntọkàn. Ẹni tí ó bá ń ṣiṣẹ́ àánú, kí ó fọ̀yàyà ṣe é.
9
Ìfẹ́ yín kò gbọdọ̀ ní ẹ̀tàn ninu. Ẹ kórìíra nǹkan burúkú. Ẹ fara mọ́ àwọn nǹkan rere.
10
Ẹ ní ìfẹ́ láàrin ara yín bíi mọ̀lẹ́bí. Ní ti bíbu ọlá fún ara yín, ẹ máa fi ti ẹnìkejì yín ṣiwaju.
11
Ẹ má jẹ́ kí ìtara yín rẹ̀yìn. Ẹ máa sin Oluwa tọkàntọkàn.
12
Ẹ máa yọ̀ nítorí ìrètí tí ẹ ní. Ẹ máa fara da ìṣòro, kí ẹ sì tẹra mọ́ adura.
13
Ẹ pín àwọn aláìní láàrin àwọn onigbagbọ ninu ohun ìní yín. Ẹ máa ṣaájò àwọn àlejò.
14
Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń ṣe inúnibíni yín, kàkà kí ẹ ṣépè, ìre ni kí ẹ máa sú fún wọn.
15
Àwọn tí ń yọ̀, ẹ bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sunkún, ẹ bá wọn sunkún.
16
Ẹ ní inú kan sí ara yín. Ẹ má ṣe gbèrò ohun gíga-gíga, ṣugbọn ẹ máa darapọ̀ mọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara yín.
17
Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere.
18
Ẹ sa ipá yín, níwọ̀n bí ó bá ti ṣeéṣe, láti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu gbogbo eniyan.
19
Ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ má máa gbẹ̀san, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún Ọlọrun láàyè láti fi ibinu rẹ̀ hàn. Nítorí Ọlọrun sọ ninu àkọsílẹ̀ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.”
20
Ó wà ní àkọsílẹ̀ mìíràn pé, “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ, bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu. Nítorí nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóo wa ẹ̀yinná ìtìjú lé e lórí.”
21
Má jẹ́ kí nǹkan burúkú borí rẹ, ṣugbọn fi ohun rere ṣẹgun nǹkan burúkú.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16