bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Romans 6
Romans 6
Yoruba 2010
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 7 →
1
Kí ni kí á wí nígbà náà? Ṣé kí a túbọ̀ máa dẹ́ṣẹ̀ kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lè máa pọ̀ sí i?
2
Kí á má rí i. Báwo ni àwa tí a ti fi ayé ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, ṣe tún lè máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀?
3
Àbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo àwa tí a ti rì bọmi lórúkọ Jesu a ti kú bí Jesu ti kú?
4
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jọ sin wá pọ̀ nígbà tí wọ́n rì wá bọmi, tí wọ́n sọ wá di òkú, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé-ayé titun gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun baba ògo ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú.
5
Bí a bá sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu Jesu ninu ikú, a óo sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu rẹ̀ ninu ajinde.
6
Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.
7
Nítorí ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
8
Bí a bá jọ bá Jesu kú, a ní igbagbọ pé a óo jọ bá Jesu yè.
9
A mọ̀ pé Kristi tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kò tún ní kú mọ́; ikú kò sì lè jọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.
10
Kíkú tí ó kú jẹ́ pé ó ti kú ikú tí ó níláti kú lẹ́ẹ̀kan; yíyè tí ó yè, ó yè fún ògo Ọlọrun.
11
Bákan náà ni kí ẹ ka ara yín bí ẹni tí ó ti kú ní ayé ẹ̀ṣẹ̀, tí ó tún wà láàyè pẹlu Ọlọrun ninu Kristi.
12
Nítorí èyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ tún rí ààyè jọba ninu ara yín tí ẹ óo fi máa fààyè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.
13
Ẹ má sì gbé ara yín sílẹ̀ bí ohun èèlò fún ẹ̀ṣẹ̀. Dípò èyí, ẹ lo ara yín fún iṣẹ́ òdodo, kí ẹ sì fi í fún Ọlọrun, ẹni tí ó lè sọ òkú dààyè.
14
Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀gá yín, nítorí ẹ kò sí lábẹ́ Òfin; abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni ẹ wà.
15
Kí ló wá kù kí á ṣe? Ṣé kí á máa dá ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé a kò sí lábẹ́ òfin, abẹ́ oore-ọ̀fẹ́ ni a wà. Ká má rí i.
16
Ẹ kò mọ̀ pé ẹrú ẹni tí ẹ bá ń gbọ́ràn sí lẹ́nu lẹ jẹ́, ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fara yín ṣẹrú fún, tí ẹ sì ń jíṣẹ́ fún? Ẹ lè fi ara yín ṣẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀, kí ó fikú san án fun yín; ẹ sì lè fìgbọràn ṣọ̀gá fún ara yín, kí ó sì fun yín ní ìdáláre.
17
Ọpẹ́ ni fỌlọrun, nítorí pé ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣẹrú ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ti wá ń fi tọkàntọkàn gba irú ẹ̀kọ́ tí a gbé kalẹ̀ níwájú yín.
18
A ti tu yín sílẹ̀ ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀ṣẹ̀, ẹ ti di ẹrú iṣẹ́ rere.
19
Mò ń fọ èdè tí ó lè yé eniyan, nítorí ọgbọ́n yín kò ì tíì kọjá ohun tí a lè fi ojú rí. Bí ẹ ti gbé ara yín fún ìwà èérí ati ìwà tinú-mi-ni-n-óo-ṣe, tí a sì fi yín sílẹ̀ kí ẹ máa ṣe bí ó ti wù yín, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ wá fi ara yín jìn fún iṣẹ́ rere, kí ẹ sìn ín fún iṣẹ́ mímọ́.
20
Nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, kò sí ohun tí ẹ bá iṣẹ́ rere dàpọ̀.
21
Èrè wo ni ẹ rí gbà lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, àfi ohun tí ń tì yín lójú nisinsinyii? Ikú ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí.
22
Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ ti bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ ti di ẹrú Ọlọrun, èrè tí ẹ óo máa rí, ti ohun mímọ́ ni. Ìyè ainipẹkun ni yóo sì yọrí sí.
23
Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16