bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Song of Solomon 1
Song of Solomon 1
Yoruba 2010
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 2 →
1
Àwọn orin tí ó dùn jùlọ tí Solomoni kọ nìwọ̀nyí:
2
Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ.
3
Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn, orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde; nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ.
4
Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá, ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀. Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ; abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!
5
Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà, mo dàbí àgọ́ Kedari, mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni.
6
Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú, oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi, wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà, ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.
7
Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́: níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko? Níbo ni wọ́n ti ń sinmi, nígbà tí oòrùn bá mú? Kí n má baà máa wá ọ kiri, láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?
8
Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin, bí o kò bá mọ ibẹ̀, ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan.
9
Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé akọ ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun Farao.
10
Nǹkan ọ̀ṣọ́ mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà, ẹ̀gbà ọrùn sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà.
11
A óo ṣe àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà, tí a fi fadaka ṣe ọnà sí lára fún ọ.
12
Nígbà tí ọba rọ̀gbọ̀kú lórí ìjókòó rẹ̀, turari mi ń tú òórùn dídùn jáde.
13
Olùfẹ́ mi dàbí àpò òjíá, bí ó ti sùn lé mi láyà.
14
Olùfẹ́ mi dàbí ìdì òdòdó igi Sipirẹsi, ninu ọgbà àjàrà Engedi.
15
Wò ó! O mà dára o, olólùfẹ́ mi; o lẹ́wà pupọ. Ojú rẹ tutù bíi ti àdàbà.
16
Háà, o mà dára o! Olùfẹ́ mi, o lẹ́wà gan-an ni. Ewéko tútù ni yóo jẹ́ ibùsùn wa.
17
Igi Kedari ni òpó ilé wa, igi firi sì ni ọ̀pá àjà ilé wa.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8