bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Song of Solomon 7
Song of Solomon 7
Yoruba 2010
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 8 →
1
Ẹsẹ̀ rẹ ti dára tó ninu bàtà, ìwọ, ọmọ aládé. Itan rẹ dàbí ohun ọ̀ṣọ́, tí ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà ṣe.
2
Ìdodo rẹ dàbí abọ́, tí kì í gbẹ fún àdàlú waini, ikùn rẹ dàbí òkítì ọkà, tí a fi òdòdó lílì yíká.
3
Ọmú rẹ mejeeji dàbí ọmọ àgbọ̀nrín meji, tí wọn jẹ́ ìbejì.
4
Ọrùn rẹ dàbí ilé-ìṣọ́ tí wọn fi eyín erin kọ́. Ojú rẹ dàbí adágún omi ìlú Heṣiboni, tí ó wà ní ẹnubodè Batirabimu. Imú rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Lẹbanoni, tí ó dojú kọ ìlú Damasku.
5
Orí rẹ dàbí adé lára rẹ, ó rí bí òkè Kamẹli, irun rẹ dàbí aṣọ elése-àlùkò tí ó ṣẹ́ léra, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ irun orí rẹ ń dá ọba lọ́rùn.
6
O dára, o wuni gan-an, olùfẹ́ mi, ẹlẹgẹ́ obinrin.
7
Ìdúró rẹ dàbí igi ọ̀pẹ, ọyàn rẹ ṣù bí ìdì èso àjàrà.
8
Mo ní n óo gun ọ̀pẹ ọ̀hún, kí n di odi rẹ̀ mú. Kí ọmú rẹ dàbí ìdì èso àjàrà, kí èémí ẹnu rẹ rí bí òórùn èso ápù.
9
Ìfẹnukonu rẹ dàbí ọtí waini tí ó dára jùlọ, tí ń yọ́ lọ lọ́nà ọ̀fun, tí ń yọ́ lọ láàrin ètè ati eyín.
10
Olùfẹ́ mi ló ni mí, èmi ni ọkàn rẹ̀ sì fẹ́.
11
Máa bọ̀, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí á jáde lọ sinu pápá, kí á lọ sùn ní ìletò kan.
12
Kí á lọ sinu ọgbà àjàrà láàárọ̀ kutukutu, kí á wò ó bóyá àjàrà ti ń rúwé, bóyá ó ti ń tanná; kí á wò ó bóyá igi Pomegiranate ti ń tanná, níbẹ̀ ni n óo ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13
Èso Mandirake ń tú òórùn dídùn jáde, ẹnu ọ̀nà wa kún fún oríṣìíríṣìí èso tí ó wuni, tí mo ti pèsè wọn dè ọ́, olùfẹ́ mi, ati tuntun ati èyí tó ti pẹ́ nílé.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8