bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Zechariah 4
Zechariah 4
Yoruba 2010
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 5 →
1
Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn.
2
Ó bi mí pé kí ni mo rí. Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje.
3
Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.”
4
Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?”
5
Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.”
6
Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi.
7
Kí ni òkè ńlá jámọ́ níwájú Serubabeli? Yóo di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Serubabeli, O óo kọ́ ilé náà parí, bí o bá sì ti ń parí rẹ̀ ni àwọn eniyan yóo máa kígbe pé, “Áà! Èyí dára! Ó dára!” ’ ”
8
OLUWA tún rán mi pé,
9
“Serubabeli tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé Ọlọrun yìí ni yóo parí rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn eniyan mi yóo mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo rán ọ sí wọn.
10
Inú àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí yóo dùn, wọn yóo sì rí okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubabeli. Àwọn fìtílà meje wọnyi ni ojú OLUWA tí ń wo gbogbo ayé.”
11
Mo bá bi í pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn igi olifi meji tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà?”
12
Mo tún bèèrè lẹẹkeji pé, “Kí ni ìtumọ̀ ẹ̀ka olifi meji, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrè wúrà meji, tí òróró olifi ń ṣàn jáde ninu wọn?”
13
Ó tún bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ohun tí wọ́n jẹ́ ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.”
14
Ó bá dáhùn, ó ní, “Àwọn wọnyi ni àwọn meji tí a ti fi òróró yàn láti jẹ́ òjíṣẹ́ OLUWA gbogbo ayé.”
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14