bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Zechariah 5
Zechariah 5
Yoruba 2010
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 6 →
1
Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú.
2
Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé “Mo rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú. Ìwé náà gùn ní ìwọ̀n ogún igbọnwọ, (mita 9); ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá (mita 4½).”
3
Ó bá sọ fún mi pé, “Ègún tí yóo máa káàkiri gbogbo ilẹ̀ náà ni a kọ sinu ìwé yìí. Láti ìsinsìnyìí lọ, ẹnikẹ́ni tí ó bá jalè ati ẹnikẹ́ni tí ó bá búra èké, a óo yọ orúkọ rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ náà.”
4
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “N óo rán ègún náà lọ sí ilé àwọn olè ati sí ilé àwọn tí wọn ń búra èké ní orúkọ mi. Yóo wà níbẹ̀ títí yóo fi run ilé náà patapata, ati igi ati òkúta rẹ̀.”
5
Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá jáde, ó ní, “Gbé ojú rẹ sókè kí o tún wo kinní kan tí ń bọ̀.”
6
Mo bèèrè pé, “Kí ni èyí?” Ó dáhùn pé, “Agbọ̀n òṣùnwọ̀n eefa kan ni. Ó dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ yìí.”
7
Nígbà tí wọ́n ṣí ìdérí òjé tí wọ́n fi bo agbọ̀n náà kúrò lórí rẹ̀, mo rí obinrin kan tí ó jókòó sinu eefa náà.
8
Angẹli náà sọ pé “Ìwà ìkà ni obinrin yìí dúró fún.” Ó ti obinrin náà pada sinu agbọ̀n eefa náà, ó sì fi ìdérí òjé náà dé e mọ́ ibẹ̀ pada.
9
Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ.
10
Mo bi angẹli náà pé, “Níbo ni wọ́n ń gbé e lọ?”
11
Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.”
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14