bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Chronicles 13
1 Chronicles 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 14 →
1
Dáfídì sì gbérò pẹ̀lú olúkúlùkù àwọn ìjòyè Rẹ̀, àwọn aláṣẹ ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn aláṣẹ́ ọgọ́rùn ún
2
Ó sì wí fún gbogbo àwọn ìjọ Ísírẹ́lì pé Tí ó bá dára lójú yín àti tí ó bá ṣe jẹ́ àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run wa, jẹ́ kí a ránṣẹ́ sí ọ̀nà jínjìn àti gbígbòòrò sí àwọn arákùnrin wa tó kù ní gbogbo àwọn agbègbè ìlú Ísírẹ́lì àti pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn nínú ìlú wọn àti pápá oko tútù, láti wá kó ara wọn jọpọ̀ sọ́dọ̀ wa.
3
Ẹ jẹ́ kí a gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA padà sọ́dọ̀ wa, nítorí wí pé àwa kò ṣe ìwádìí nípa Rẹ̀ ní àsìkò ìjọba Ṣọ́ọ̀lù
4
Gbogbo ìjọ náà sì gbà láti ṣe èyí nítorí ó dàbí wí pé ó tọ lójú gbogbo àwọn ènìyàn.
5
Nígbà náà ni Dáfídì pe gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ, láti ọ̀dọ̀ Ṣíhórì ní Éjíbítì lọ sí Lébò ní ọ̀nà à bá wọ Hámátì, láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà láti Kiriati Jéárímù.
6
Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú Rẹ̀ lọ sí Báláhì ti Júdà (Kiriati-Jéárímù) láti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run OLÚWA tí a fi orúkọ Rẹ̀ pè, tí ó jókòó láàrin kérúbù-gòkè wá.
7
Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run láti ilé Ábínádábù lórí kẹ̀kẹ́ túntún, Usà àti Áhíò ń sọ́ ọ.
8
Dáfídì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú ohun èlò orin olóhùn gooro, písátérù, tíńbálì, síńbálì àti ìpè.
9
Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ pakà ti Kídónì, Úsà na ọwọ́ Rẹ̀ síta láti di àpótì ẹ̀rí OLÚWA mú, nítorí màlúù kọ̀ṣẹ̀.
10
Ìbínú OLÚWA, sì ru sí Úsà, ó sì lùú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ Rẹ̀ lórí Àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
11
Nígbà náà Dáfídì sì bínú nítorí ìbínú OLÚWA ké jáde lórí Úsá, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní péresì-Ùsà.
12
Dáfídì sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì bèèrè pé, Báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Olórun sí ọ̀dọ̀ mi?
13
Kò gbé àpótí ẹ̀rí náà wá sí ọ̀dọ̀ ará Rẹ̀ ní ìlú ti Dáfídì dípò èyí, ó sì gbé e sí ẹ̀gbé, sí ilé Obedi-Édómù ará Gítì.
14
Àpótí ẹ̀rí OLÚWA sì wà lọ́dọ̀ àwon ará ilé Obedi-Édómù ní ilé Rẹ̀ fún oṣù mẹ́ta, OLÚWA sì bùkún agbo ilé àti gbogbo ohun tí ó ní.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29