bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Corinthians 16
1 Corinthians 16
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
1
Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí fi fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe.
2
Ní ọjọ́ kínní ọ̀sẹ̀, kí olukúlúkù yín fí sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé.
3
Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jérúsálẹ́mù.
4
Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.
5
Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrin Makedóníà: nítorí èmi yóò kọjá láàrin Makedóníà.
6
Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbi kí n tílẹ̀ lo àkókò òtúútúú, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ.
7
Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọja lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́
8
Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Éfésù títí dí Pẹ́ńtíkósìtì.
9
Nítorí pé ilẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣi sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀ta tí ń bẹ.
10
Ǹjẹ́ bí Tímótíù bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù: nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe.
11
Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.
12
Ṣùgbọ́n ní ti Àpólò arákùnrin wa, mo bẹ́ẹ̀ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsìnyìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbá tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.
13
Ẹ máa ṣọra, ẹ dúró gbọingbọin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára.
14
Ẹ máa ṣe gbogbo nínú ìfẹ́.
15
Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ sá mọ ilé Sítéfánà, pé àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jésù ní Ákáyà, àti pé, wọn sì tí fí ará wọn fún iṣẹ́-iránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́.
16
Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbásiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá.
17
Mo láyọ̀ fún wíwá Sítéfánà àti Fórítúnátù àti Ákáyákù: nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fí kún un.
18
Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba ìru àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.
19
Àwọn ìjọ ni Ásíà kí í yín, Àkúílà àti Pìrìsílà kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.
20
Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín, ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.
21
Ìkíni ti èmi Pọ́ọ̀lù, láti ọwọ́ èmi tìkáraàmi wá.
22
Bí ẹníkẹ́ní kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kírísítì Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!
23
Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!
24
Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kírísítì Jésù. Àmín.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16