bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Corinthians 8
1 Corinthians 8
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 9 →
1
Ní ìsinsinyìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀, ìmọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní i gbéni ró.
2
Bí ẹnkẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀.
3
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí a ṣí lójú sí ìmọ̀ àti òye Ọlọ́run.
4
Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láì ṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kansoso ní ń bẹ, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo.
5
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ Ọlọ́run kékèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “Ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “Olúwa” wa).
6
Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan soso Jésù Kírísítì, nípaṣẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípaṣẹ̀ rẹ̀.
7
Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsinyìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rì-ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́.
8
Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa buru julọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.
9
Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsí ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má baà mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í se onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, subú sínú ẹ́sẹ̀.
10
Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti iwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, lati jẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìsà?
11
Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kírísítì kú fún.
12
Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arakùnrin rẹ̀ tí ẹ sì n pá ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́sẹ̀ sí Kírísítì jùlọ.
13
Nítorí nàá, bí ẹran tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bá máa mú arákùnrin mi dẹ́ṣẹ̀, èmi kì yóò jẹ́ ẹran mọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè, nítorí n kò fẹ́ kí arákùnrin mi ṣubú sìnù ẹ̀ṣẹ̀.
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16