bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Samuel 19
1 Samuel 19
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 20 →
1
Ṣọ́ọ̀lù sọ fún Jónátanì ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dáfídì. Ṣùgbọ́n Jónátanì fẹ́ràn Dáfídì púpọ̀
2
Ó sì kìlọ̀ fún un pé, “Baba mi Ṣọ́ọ̀lù wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsí ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sá pamọ́ sí ibẹ̀.
3
Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”
4
Jónátanì sọ̀rọ̀ rere nípa Dáfídì fún Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.
5
Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Fílístínì. OLÚWA ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Èéṣe nígbà náà tí ìwọ yóò fi ṣe ohun búburú sí ọkùnrin aláìṣẹ̀ láìnídìí?”
6
Ṣọ́ọ̀lù fetísí Jónátanì, ó sì búra báyìí, “Níwọ̀n ìgbà tí OLÚWA bá ti ń bẹ láàyè, a kì yóò pa Dáfídì.”
7
Nítorí náà Jónátanì pe Dáfídì, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì sì wà lọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.
8
Lẹ́ẹ̀kàn an sí i ogun tún wá, Dáfídì sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Fílístínì jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.
9
Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá sí orí Ṣọ́ọ̀lù bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ ọ rẹ̀. Bí Dáfídì sì ti fọn ohun èlò orin olókùn,
10
Ṣọ́ọ̀lù sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dáfídì yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ṣọ́ọ̀lù ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dáfídì sì fi ara pamọ́ dáradára.
11
Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn sí ilé Dáfídì láti sọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Míkálì, ìyàwó Dáfídì kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí ì rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a ó ò pa ọ́.”
12
Nígbà náà Míkálì sì gbé Dáfídì sọ̀kalẹ̀ ó sì fi aṣọ bò ó.
13
Míkálì gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀.
14
Nígbà ti Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dáfídì, Míkálì wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.”
15
Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dáfídì ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.”
16
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà.
17
Ṣọ́ọ̀lù wí fún Míkálì pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀ta mi sálọ tí ó sì bọ́?” Míkálì sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?”
18
Nígbà tí Dáfídì ti sá lọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà ó sì sọ gbogbo ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ti ṣe fún un. Òun àti Sámúẹ́lì lọ sí Náíótì láti dúró níbẹ̀.
19
Ọ̀rọ̀ sì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá pé, “Dáfídì wà ní Náíótì ní Rámà,”
20
ó sì rán àwọn ènìyàn láti fi agbára mú u wá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tí ń ṣọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Sámúẹ́lì dúró níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí, ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá sórí àwọn arákùnrin Ṣọ́ọ̀lù àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀.
21
Wọ́n sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣọtẹ́lẹ̀.
22
Nígbẹ̀yìn, òun fúnra rẹ̀ sì lọ sí Rámà ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Ṣékù. Ó sì béèrè, “Níbo ni Sámúẹ́lì àti Dáfídì wà?” Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Náíótì ní Rámà.”
23
Ṣọ́ọ̀lù sì lọ sí Náíótì ni Rámà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Náíótì.
24
Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ níwájú Sámúẹ́lì. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni?”
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 20 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31