bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Samuel 31
1 Samuel 31
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
1
Àwọn Fílístínì sì bá Ísírẹ́lì jà: àwọn ọkùnrin Ísírẹlì sì sá níwájú àwọn Fílístínì, àwọn tí ó fi ara pa sì ṣubú ní òkè Gílíbóà.
2
Àwọn Fílístínì sì ń lépa Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Fílístínì sì pa Jónátanì àti Ábínádábù, àti Mélíkísúà, àwọn ọmọ Ṣọ́ọ̀lù.
3
Ìjà náà sì burú fún Ṣọ́ọ̀lù gidigidi, àwọn tafàtafà si ta á ní ọfà, o sì fi ara pa púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tafàtafà.
4
Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún ẹni tí o ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lù ú.
5
Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si ríi pé Ṣọ́ọ̀lù kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pá ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀.
6
Ṣọ́ọ̀lù sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.
7
Nígbà ti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí ó wà lápa kejì àfonífojì náà, àti àwọn ẹni tí ó wà lápá kejì Jódánì, rí pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá, àti pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti kú, wọ́n sì fí ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá, àwọn Fílístínì sí wá, wọ́n sì jókòó si ìlú wọn.
8
Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Fílístínì dé láti bọ́ nǹkán tí ń bẹ lára àwọn tí ó kù, wọ́n sì rí pé, Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ṣubú ni òkè Gílíbóà.
9
Wọ́n sì gé orí rẹ̀, wọ́n sì bọ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ lọ ilẹ̀ Fílístínì káàkiri, láti máa sọ ọ́ nígbángba ni ilé òrìṣà wọn, àti láàrin àwọn ènìyàn.
10
Wọ́n sì fi ìhámọ́ra rẹ̀ sí ilé Áṣítárótì: wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ odi Bétísánì.
11
Nígbà tí àwọn ará Jabesi-Gílíádì sì gbọ́ èyí tí àwọn Fílístínì ṣe sí Ṣọ́ọ̀lù.
12
Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Ṣọ́ọ̀lù, àti okú àwọn ọmọ bibi rẹ̀ kúrò lára odi Bétísánì, wọ́n sì wá sí Jábésì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.
13
Wọ́n sì kó egungun wọn, wọ́n sì sin wọ́n lábẹ́ igi kan ní Jábésì, wọ́n sì gba ààwẹ̀ ní ijọ́ méje.
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31