bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Acts 10
Acts 10
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 11 →
1
Ọkùnrin kan sì wà ni Kesaríà ti a ń pè ní Kọ̀nélíù, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Ítálì.
2
Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilé tilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.
3
Níwọ̀n wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere ańgẹ́lì Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Kọ̀nélíù!”
4
Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kí ni, Olúwa?” Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run fún ìrántí.
5
Sì rán ènìyàn nísinsìnyìí lọ sí Jópà, kí wọn sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù.
6
Ó wọ̀ sí ilé Símónì aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”
7
Nígbà tí ańgẹ́lì náà tí ó bá Kọ̀nélíù sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, ati ọmọ ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo.
8
Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Jópà. A fi ran hàn Pétérù pẹ̀lú.
9
Ni ijọ́ kéjì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Pétérù gun òkè ilé lọ gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́:
10
Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran.
11
Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun-èlò kan si sọ̀kálẹ̀ bí gọ̀gọ̀wú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀:
12
Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹrankọ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, ati ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.
13
Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Pétérù; máa pa kí o sì má a jẹ.”
14
Ṣùgbọn Pétérù dáhùn pé, “Àgbẹdọ̀, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ ati aláìmọ́ kan rí.”
15
Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ́méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀ nù, ìwọ má ṣe pè é léèwọ̀ mọ́.”
16
Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.
17
Bí Pétérù sì ti ń dààmù nínú ara rẹ̀ bí a ìbá ti mọ̀ ìran tí oun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Kọ̀nélíù dé. Wọ́n ń bèèrè ilé Símónì, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà.
18
Wọn nahùn ń bèèrè bí Símónì tí a ń pè ní Pétérù, wọ̀ níbẹ̀.
19
Bí Pétérù sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.
20
Njẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kọminú ohunkohun: nítorí èmi ni ó rán wọn.”
21
Nígbà náà ni Pétérù sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí tẹ̀ ti ẹ fi wá?”
22
Wọ́n sì wí pé, “Kọ̀nẹ́líù balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ́ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ ańgẹ́lì mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”
23
Nígbà náà ni ó pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò. Níjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, nínú àwọn arákùnrin ní Jopa sì bá a lọ pẹ̀lú.
24
Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesaríà, Kọ̀nélíù sì ti ń rétí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.
25
Ó sì ṣe bí Pétérù ti ń wọlé, Kọ̀nélíù pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un.
26
Ṣùgbọ́n Pétérù gbé e dìde, ó ni, “Dìde; ènìyàn ni èmi tìkárami pẹ̀lú.”
27
Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé, ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ.
28
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilé mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́.
29
Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo bèèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”
30
Kọ̀nẹ́líù sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi.
31
Ó sì wí pé, ‘Kọ̀nélíù, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run.
32
Ǹjẹ́ ránsẹ́ lọ sí Jópà, kí ó sì pe Símónì wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Pétérù; ó wọ̀ ní ilé Símónì aláwọ léti òkun: nígbà ti ó bá dé, ẹni yóò sọ̀rọ̀ fún ọ.’
33
Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsìnyìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”
34
Pétérù sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojusajú ènìyàn.
35
Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣisẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.
36
Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Isírẹ́lì, nígbà tí a wàásù àlàáfíà nípa Jésù Kírísítì (Òun ni Olúwa ohun gbogbo)
37
Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Jùdíà, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Gálílì, lẹ́yìn bamitíìsímù ti Jòhánù wàásù rẹ̀.
38
Àní gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run Ẹ̀mi Mímọ́ àti agbára; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí Èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
39
“Àwa sì ni ẹlẹ́rì gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerúsálémù. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.
40
Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba.
41
Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti lọ́wọ́ Ọlọ́run yàn tẹ́lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jindé kúrò nínú òkú.
42
Ó sì paṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe Onídàjọ́ ààyè àti òkú.
43
Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”
44
Bí Pétérù sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.
45
Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti ìkọlà tí wọ́n bá Pétérù wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú.
46
Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo. Nígbà náà ni Pétérù dáhùn wí pé,
47
“Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin omi, kí a má bamítíìsì àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?”
48
Ó sì pàsẹ kí a bamitíìsì wọn ni orúkọ Jésù Kírísitì. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ijọ́ mélòókan.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28