bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Acts 12
Acts 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 13 →
1
Ní àkókò ìgbà náà ni Hérọ́dù ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan lójú nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú.
2
Ó sì fi idà pa Jákọ́bù arakùnrin Jòhánù.
3
Nígbà tí ó sì rí pé èyí ó dùn mọ́ àwọn Júù nińu, ó sì nawọ́ mú Pétérù pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà ọjọ́ àkàrà àìwú.
4
Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Hẹ́rọ́dù ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrekọjá fún ìdájọ́.
5
Nítorí náà wọn fi Pétérù pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un.
6
Ní òru náà gan-an ti Héródù ìbá sì mú un jáde, Pétérù ń sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀sọ́ sí wà lẹ́nu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà.
7
Sì wò ó, ańgẹ́lì Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ́ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Pétérù pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Pétérù.
8
Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Pétérù sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!”
9
Pétérù sì jáde, ó ń tọ ọ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣèbí òun wà lójú ìran.
10
Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ ìkínní àti ìkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tikararẹ̀ sí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà ańgẹ́lì náà sì fi í sílẹ̀ lọ.
11
Nígbà tí ojú Pétérù sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán ańgẹ́lì rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Héródù àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń rétí!”
12
Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Johánù, tí àpélè rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ pejọ sí, tí wọn ń gbàdúrà.
13
Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Ródà wá láti dáhùn.
14
Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Pétérù, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sí sọ pé, Pétérù dúró ní ẹnu-ọ̀nà.
15
Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Ańgẹ́lì rẹ̀ ni!”
16
Ṣùgbọ́n Pétérù ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n.
17
Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé “Ẹ ro èyí fún Jákọ́bù àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn.
18
Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrin àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó débá Pétérù.
19
Nígbà tí Héródù sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀sọ́, ó paṣẹ pé, kí a pa wọ́n. Hẹ́rọ́dù sì sọ̀kalẹ̀ láti Jùdíà lọ sí Kesaríà, ó sì wà níbẹ́ fún ìgbà díẹ̀.
20
Héródù sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tírè àti Sídónì; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀sọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bílásítù ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀ẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tiwọn ti ń gba oúnjẹ.
21
Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Hẹ́rọ́dù sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba.
22
Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!”
23
Lójúkan náà, nítorí ti Hẹ́rọ́dù kò fi ògo fún Ọlọ́run, ańgẹ́lì Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.
24
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.
25
Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sì padà wá láti Jerúsálémù, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Jòhánù ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Máàkù wá pẹ̀lú wọn.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28