bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Amos 3
Amos 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 4 →
1
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Éjíbítì:
2
“Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí; nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ níyà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”
3
Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti gbà láti ṣe é?
4
Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbo, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú?
5
Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?
6
Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wú ìlú kò ha ṣe OLÚWA ni ó fà á?
7
Nítòótọ́ OLÚWA Ọlọ́run kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn sí àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.
8
Kìnnìún ti bú ramúramù ta ni kì yóò bẹ̀rù? OLÚWA Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọtẹ́lẹ̀?
9
Ẹ kéde ní ààfin Áṣídódù àti ní ààfin ní ilẹ̀ Éjíbítì. “Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samáríà; Kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrin rẹ̀ àti ìnílára láàrin àwọn ènìyàn rẹ.”
10
“Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni OLÚWA wí, “Ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”
11
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”
12
Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “Bí olusọ-àgùntan ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìun tàbí ẹ̀là eti kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí ń gbé Samáríà kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Dámásíkù.”
13
“Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jákọ́bù,” ni OLÚWA wí, OLÚWA Ọlọ́run alágbára.
14
“Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Ísírẹ́lì lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Bétélì run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀.”
15
“Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ẹ̀ẹ̀rùn; ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run,” ni OLÚWA wí.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
Recommended Reading
Commentary
Amos Commentaries
→
Devotional
Amos Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→