bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Amos 6
Amos 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 7 →
1
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Síónì àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaríà àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì máa ń tọ̀ ọ́ wá
2
Ẹ lọ Kálínì kí ẹ lọ wò ó Kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Ámátì ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gátì ní ilẹ̀ Fílístínì Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju ti yín lọ bí?
3
Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòòsí
4
Ẹ̀yin sùn lé ibusùn tí a fi eyín erin ṣe Ẹ sì tan ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn Ẹ̀yin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn yín jẹ Ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrin agbo wọn jẹ
5
Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dáfídì Ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ̀ àwọn ohun èlò orin
6
Ẹ̀yín mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káànú ilé Jósẹ́fù tí o di ahoro
7
Nitorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àwẹ̀jẹwẹ̀mú àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò
8
OLÚWA ọ̀gá ògo ti búra fúnra rẹ̀ OLÚWA Ọlọ́run alágbára sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jákọ́bù n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀ Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”
9
Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá sẹkù nínú ile kan, àwọn náà yóò kú
10
Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béérè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó farapamọ́ níbẹ̀, “Njẹ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ OLÚWA.”
11
Nítorí OLÚWA tí pa àṣẹ náà, Oun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú Àti sísán kọlu ilé kékèké.
12
Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi ẹṣin kọ́ ni lórí àpáta bí? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí ọ̀títọ́ padà sí májèlé Ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò.
13
Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lódábárì Ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í se agbára wa ni àwa fi gba Kánáímù?”
14
Nítorí OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí pé, “Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Ísírẹ́lì, tí yóò máa ni ọ́ lára ní gbogbo ọ̀nà láti ẹnu ọ̀nà ìwọlé Hámátì títí dé àfonífojì aginjù.”
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
Recommended Reading
Commentary
Amos Commentaries
→
Devotional
Amos Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→