bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezra 1
Ezra 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 2 →
1
Ní ọdún kìn-ní-ní Ṣáírúsì, ọba Páṣíà, kí a lè mú ọ̀rọ̀ OLÚWA tí Jeremáyà sọ ṣẹ, OLÚWA ru ọkàn Ṣáírúsì ọba Páṣíà sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbégbé ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:
2
Èyí ni ohun tí Sáírúsì ọba Páṣíà wí pé: OLÚWA, Ọlọ́run ọ̀run, ti fún mi ní gbogbo ìjọba ayé. Ó sì ti yàn mí láti kọ́ tẹ́ḿpìlì OLÚWA fún un ní Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà.
3
Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ láàárin yín—kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Júdà, láti kọ́ tẹ́ḿpìlì OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Ọlọ́run tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.
4
Kí àwọn ènìyàn ní ibikíbi tí ẹni tí ó lù ú bá ń gbé kí ó fi fàdákà àti wúrà pẹ̀lú ohun tí ó dára àti ẹran-ọ̀sìn, pẹ̀lú ọrẹ àtinúwá ràn án lọ́wọ́ fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù.
5
Nígbà náà àwọn olórí ìdílé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì—olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run ti fọwọ́ tọ́ ọkàn rẹ̀—múra láti gòkè lọ láti kọ ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù.
6
Gbogbo àwọn aládùúgbò wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ohun èlò ti fàdákà àti wúrà, pẹ̀lú onírúurú ohun ìní àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn iyebíye, ní àfikún gbogbo àwọn ọrẹ àtinúwá.
7
Ní àfikún, ọba Ṣáírúsì mú àwọn ohun èlò tí ó jẹ́ ti ilé OLÚWA jáde wá, tí Nebukadinésárì ti kó lọ láti Jérúsálẹ́mù tí ó sì ti kó sí ilé òrìṣà rẹ̀.
8
Ṣáírúsì ọba Páṣíà pàṣẹ fún Mítúrédátì olùṣọ́ ilé ìṣúra láti kó wọn jáde, ó sì kà wọ́n fún Ṣéṣíbásárì ìjòyè Júdà.
9
Èyí ni iye wọn: Ọgbọ̀n àwo wúrà — (30) ẹgbẹ̀rún àwo fàdákà — (1000) Àwo ìrúbọ fàdákà mọ́ kàndínlọ́gbọ̀n — (29)
10
ọgbọ̀n àdému wúrà — (30) irinwó ó lé mẹ́wàá oríṣìí àdému fàdákà mìíràn — (410) ẹgbẹ̀rún kan àwọn ohun èlò mìíràn — (1000)
11
Gbogbo ohun èlò wúrà àti ti fàdákà ní àpapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn ún-ó-lé-irinwó (5,400). Ṣéṣíbáṣárì kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí wá pẹ̀lú àwọn ìgbèkùn tí ó gòkè wá láti Bábílónì sí Jérúsálẹ́mù.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10