bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezra 2
Ezra 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 3 →
1
Wàyí o, wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn agbègbè Júdà tí ó gòkè wá láti ìgbèkùn láàrin àwọn tí a kó lọ, ẹni tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì ti fi agbára mú ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà. Olúkúlùkù sí ìlú rẹ̀,
2
Àwọn wọ̀nyí bá Ṣérúbábélì, Jéṣúà, Nehemáyà, Ṣéráíyà, Réláéyà, Modekáyì, Bílíṣánì, Mísífárì, Bígífáyì, Réhúmì àti Báánà wá): Iye àwọn ọkùnrin àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì: —
3
Àwọn ìran Páróṣì jẹ́ ẹgbọ̀kànlá ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n — (2,172) —
4
Ìran Ṣéfátíyà jẹ́ irinwó ó dín méjìdínlọ́gbọ̀n — (372) —
5
Ìran Árà jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó-dín-mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n — (775) —
6
Ìran Páhátì-Móábù (nípaṣẹ̀ àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù) jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin-ó-le-méjìlá — (2,812) —
7
Ìran Élámì jẹ́ àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀fà-ó-lé-mẹ́rin — (1,254) —
8
Ìran Ṣátù jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rún — (945) —
9
Ìran Ṣákáì jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin — (760) —
10
Ìran Bánì jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta-ó-lé méjì — (642) —
11
Ìran Bébáì jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó-lé-mẹ́talélógún — (623) —
12
Ìran Áṣígádì jẹ́ ẹgbẹ̀fa-ó-lé méjìlélógún — (1,222) —
13
Ìran Ádóníkámù jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀tà-ó-lé mẹ́fà — (666) —
14
Ìran Bígífáyì jẹ́ ẹgbàá-ó-lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta — (2,056) —
15
Ìran Ádínì jẹ́ Àádọ́talénírínwó-ólé mẹ́rin — (454) —
16
Ìran Átérì nípaṣẹ̀ Heṣekáyà jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rin — (78) —
17
Ìran Bésáì jẹ́ Ọ̀rùndínnírínwó-ólé-mẹ́ta — (323) —
18
Ìran Jórà jẹ́ méjìléláàdọ́fà — (112) —
19
Ìran Hásúmì jẹ́ igba ólé mẹ́talélógún — (223) —
20
Ìran Gíbárì jẹ́ márùndínlọ́gọ́run — (95)
21
Àwọn ọkùnrin Bétílẹ́hẹ́mù jẹ́ mẹ́talélọ́gọ́fà — (123) —
22
Ìran Nétófà jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́tà — (56) —
23
Ìran Ánátótì jẹ́ méjìdínládóje — (128) —
24
Ìran Áṣímáfétì jẹ́ méjìlélógójì — (42) —
25
Ìran Kíríátì Jéárímù, Éfírà àti Bérótì jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ólé-mẹ́ta — (743) —
26
Ìran Rámà àti Gébà jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ó-lé mọ́kànlélógún — (621) —
27
Ìran Míkímásì jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà — (122) —
28
Ìran Bétélì àti Áì jẹ́ igba-ólé mẹ́talélógún — (223) —
29
Ìran Nébò jẹ́ méjìléláàdọ́ta — (52) —
30
Ìran Mágíbísì jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́jọ — (156) —
31
Ìran Élámù jẹ́ àádọ́ta lé-lẹ́gbẹ̀fà-ó-lé-mẹ́rin — (1,254) —
32
Ìran Hárímù jẹ́ ọ̀rìndínnírínwó — (320) —
33
Ìran Lódì, Hádídì àti Ónò jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó-lé-márùn-ún — (725) —
34
Ìran Jẹ́ríkò jẹ́ ọ̀tàdínnírínwó-ó-lé márùn-ún — (345) —
35
Ìran Ṣénà jẹ́ egbéjìdínlógún-ó-lé-ọgbọ̀n — (3,630)
36
Àwọn Àlùfáà: — Àwọn Ìran Jédáíyà (nípaṣẹ̀ ìdílé Jéṣúà) jẹ́ ogúndínlẹ́gbẹ̀rún ó-dín-méje — (973) —
37
Ìran Ímérì jẹ́ àádọ́ta lélẹ́gbẹ̀rún-ó-lé méjì — (1,052) —
38
Ìran Páṣúrì jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀fà ó-lé-méje — (1,247) —
39
Ìran Hárímù jẹ́ ẹgbẹ̀rin-ó-lé mẹ́tadínlógún — (1,017)
40
Àwọn ará Léfì: — Àwọn Ìran Jésúà àti Kádíméì (ti ìdílé Hódáfíà) jẹ́ mẹ́rìnléláàdọ́rin — (74)
41
Àwọn akọrin: — Àwọn Ìran Áṣáfì jẹ́ méjìdínláádóje — (128)
42
Àwọn aṣọ́bodè: — Áwọn ara Ṣálúmì, Átérì, Tánímónì, Ákúbù, Hátítà àti Ṣóbíà jẹ́ mọ́kàndínlógóje — (139)
43
Àwọn ìránṣẹ́ Tẹ́ḿpìlì: — Àwọn ìran — Ṣíhà, Hásúfà, Tábáótì, —
44
Kérósì, Ṣíáhà, Pádónì, —
45
Lébánà, Hágábà, Ákúbù, —
46
Hágábì, Ṣálímáì, Hámánì, —
47
Gídélì, Gáhánì, Réáíyà, —
48
Résénì, Nékódà, Gásámù, —
49
Úṣà, Páséà, Bésáì, —
50
Áṣínà, Méúnímì, Néfúsímù, —
51
Bákíbúkì, Hákúfà, Háríhúrì. —
52
Básílútì, Méhídà, Hárísà, —
53
Báríkósì, Ṣísérà, Témà,
54
Nésíà àti Hátífà —
55
Àwọn Ìran tí ìránṣẹ́ Sólómónì: — Àwọn ìránṣẹ́ — Ṣótaì, Hásóférétì, Pérúdà, —
56
Jálà, Dáríkónì, Gídè, —
57
Ṣépátíà, Hátílì, — Pókérì-Háṣébáímì àti Ámì
58
Àwọn ìrańṣẹ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran àwọn ìranṣẹ́ Ṣólómónì jẹ́ irinwó-ó-dín-mẹ́jọ — (392)
59
Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti Télì-Mélà, Télì-Háríṣà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò le fihàn pé àwọn ìdílé wọn ṣèẹ̀wá láti ìran Ísírẹ́lì: —
60
Àwọn ìran — Déláyà, Tóbíyà àti Nékódà jẹ́ àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta-ó-lé-méjì — (652)
61
Pẹ̀lú láti àárin àwọn àlùfáà: — Àwọn ìránṣẹ — Hóbátà, Hákósì àti Báríṣíláì (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Báríṣíláì ará Gílíádì a sì ń fi orúkọ náà pè é). —
62
Àwọn wọ̀nyí wá ìwé ìrántí ìdílé wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n kún ara àlùfáà nítorí, a kà wọ́n sí aláìmọ́.
63
Baálẹ̀ pa á láṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ nínú oúnjẹ mímọ́ jùlọ títí tí àlùfáà kan yóò fi ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú Úrímù àti Túmímù.
64
Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ (42,360) ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-òjìdínnírinwó.
65
Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin.
66
Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín mẹ́rin ẹṣin (736); ìbaka òjìlélúgba-ó-lé-márùn-ún (245)
67
Ràkúnmí jẹ́ irinwó-ó-lé-márùndínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rínlélọ́gbọ̀n-ó-dín-ọgọ́rin (6,720).
68
Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá silẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.
69
Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dírámà wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.
70
Àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé OLÚWA ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10