bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Galatians 4
Galatians 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 5 →
1
Ǹjẹ́ ohun tí mo ń wí ni pé, níwọ̀n ìgbà tí àrólé náà bá wà ní èwe, kò yàtọ̀ nínú ohunkóhun sí ẹrú bí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa ohun gbogbo.
2
Ṣùgbọ́n ó wà lábẹ́ olùtọ́jú àti ìríjú títí àkókò tí baba ti yàn tẹ́lẹ̀.
3
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, nígbà tí àwa wà ní èwe, àwa wà nínú ìdè lábẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá.
4
Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin.
5
Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ,
6
Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábà, Baba.”
7
Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Kírísítì.
8
Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti sìnrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ẹ̀dá.
9
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà tí ẹ̀yin ti mọ Ọlọ́run tan tàbí kí a ṣá kúkú wí pé ẹ di mímọ́ fún Ọlọ́run, è é ha ti rí tí ẹ tún fi yípadà sí aláìlera àti alágbe ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí ẹ̀yin tún fẹ́ padà wá sìnrú?
10
Ẹ̀yin ń kíyèsí ọjọ́ àti àkókò, àti ọdún.
11
Ẹ̀rù yin ń bà mí, kí o má bà ṣe pé lásán ni mo ṣe làálàá lórí yín.
12
Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi: nítorí èmi dà bí ẹ̀yin: èyin kò ṣe mí ní ibi kan.
13
Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́.
14
Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, àní bí Kírísítì Jésù.
15
Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà há dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, ìbá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi.
16
Ǹjẹ́ mo há di ọ̀ta yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí?
17
Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere; wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn.
18
Ṣùgbọ́n ó dára láti máa fi ìtara wáni fún rere nígbà gbogbo, kì í sìí ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan.
19
Ẹ̀yin ọmọ mi kékèké, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kírísítì nínú yín.
20
Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsìnyìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín.
21
Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin.
22
Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Ábúráhámù ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin.
23
Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira-obìnrin ni a bí nípa ìlérí.
24
Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní méjẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sínáì wá, tí a bí lóko-ẹrú, tí í ṣe Hágárì.
25
Nítorí Hágárì yìí ni òkè Sínáì Árábíà, tí ó sì dúró fún Jerúsálémù tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko-ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.
26
Ṣùgbọ́n Jerúsálémù ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa.
27
Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Má a yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”
28
Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Ísáákì.
29
Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsìnyìí.
30
Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrú-bìnrin náà jáde àti ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ ẹrú-bìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira-obìnrin jogún pọ̀.”
31
Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrú-bìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6