bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Galatians 5
Galatians 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 6 →
1
Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin nínú òmìnira náà èyí tí Kírísítì fi sọ wá di òmìnira, kí ẹ má sì ṣe tún fi ọrùn bọ̀ àjàgà ẹrú mọ́.
2
Kíyèsí i, èmi Pọ́ọ̀lù ni ó wí fún yín pé, bí a bá kọ yín nílà, Kírísítì kì yóò lérè fún yín ní ohunkóhun.
3
Mo sì tún sọ fún olúkúlùkù ènìyàn tí a kọ ní ilà pé, ó di ajigbésè láti pa gbogbo òfin mọ́.
4
A ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Kírísítì, ẹ̀yin tí ń fẹ́ kí a dá yín láre nípa òfin; pé ẹ ti ṣubú kúrò nínú oore-ọ̀fẹ́.
5
Nítorí nípa Ẹ̀mí àwa ń fi ìgbàgbọ́ dúró de ìrètí òdodo.
6
Nítorí nínú Kírísítì Jésù ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà; ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.
7
Ẹ̀yin ti ń sáré dáradára; ta ni dí yin lọ́wọ́ láti ṣe ìgbọ́ran sí òtítọ́?
8
Ìyípadà yìí kò ti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó pè yín wá.
9
Ìwúkàrà díẹ̀ ní í mú gbogbo ìyẹ̀fun wú.
10
Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́.
11
Ṣùgbọ́n, ará, bí èmi bá ń wàásù ìkọlà síbẹ̀, kín ni ìdí tí a fi ń ṣe inúnibíni sí mi síbẹ̀? Ǹjẹ́ ìkọsẹ̀ àgbélébùú ti kúrò.
12
Èmi ìbá fẹ́ kí àwọn tí ń yọ yín lẹ́nu tilẹ̀ gé ẹ̀yà-ara wọn kan kúrò.
13
Nítorí a ti pè yín sí òmìnira, ará kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yín bí àǹfààní sípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejjì yín.
14
Nítorí pé a kó gbogbo òfin já nínú èyí pé, “Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”
15
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.
16
Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ́ ti ara ṣẹ.
17
Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má baà lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́.
18
Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mi samọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.
19
Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tíí ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà,
20
Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórira, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtara-ẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́-òdí.
21
Àrankan, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde-òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
22
Ṣùgbọ́n èèso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,
23
Ìwà-tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí,
24
Àwọn tí í ṣe ti Kírísítì Jésù ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.
25
Bí àwa bá wà láàyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí.
26
Ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa ṣògo-asán, kí a má mú ọmọnìkejì wa bínú, kí a má ṣe ìlara ọmọnìkejì wa.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6