bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jonah 2
Jonah 2
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 3 →
1
Ngbà náà ni Jónà gbàdúrà sí OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá,
2
Ó sì wí pé: “Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí OLÚWA, òun sì gbọ́ ohùn mi. Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún iraǹwọ́, ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.
3
Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárin òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi ré kọjá lórí mi.
4
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘a ta mí nù kúrò níwájú rẹ; ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ èmi yóò tún máa wo ìhà tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.’
5
Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn; ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò wé mi lórí.
6
Èmi ṣọ̀kalẹ̀ lọ sí ìṣàlẹ̀ àwọn òkè ńlá; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, OLÚWA Ọlọ́run mi.
7
“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, OLÚWA, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.
8
“Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀.
9
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rúbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Igbàlà wá láti ọdọ OLÚWA.’ ”
10
OLÚWA sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jónà sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4