bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Jonah 4
Jonah 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
1
Ṣùgbọ́n ó ba Jónà nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀.
2
Ó sì gbàdúrà sí OLÚWA, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, OLÚWA, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyi nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítórí èyí ni mo ṣé sá lọ sí Tásísí ní ìṣáájú: nitori èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà.
3
Ǹjẹ́ báyìí, OLÚWA, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ.”
4
Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”
5
Jónà sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni ibòòji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà.
6
OLÚWA Ọlọ́run sì pesè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jónà; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jónà sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà.
7
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ.
8
Ó sì ṣe, nígbà tí òòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jónà lórí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láàyè lọ.”
9
Ọlọ́run sì wí fún Jónà pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?” Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, Ó tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”
10
Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan.
11
Ṣùgbọ́n Nínéfè ní jù ọ̀kẹ́-mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun-ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ilú ńlá náà?”
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
All chapters:
1
2
3
4