bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Philippians 3
Philippians 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 4 →
1
Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ àìléwu.
2
Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́-búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà.
3
Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kírísítì Jésù, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran ara.
4
Bí èmi tìkárami pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀:
5
Ẹnii tí a kọ nílà ní ijọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Ísírẹ́lì wá, láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Hébérù láti inú Hébérù wá; nítorí, ní ti òfin Farisí ni èmi;
6
Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibínu sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.
7
Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kírísítì.
8
Nítòótọ́ láìṣe àní-àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kírísítì Jésù Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní láárí, kí èmi lè jèrè Kírísítì,
9
Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkarami, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kírísítì, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́;
10
Kí èmi lè mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábàápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá faramọ́ ọn nínú ikú rẹ̀;
11
Bí ó lè ṣe é ṣe kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.
12
Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa ǹṣó, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mí mú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kírísítì Jésù wá.
13
Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná: Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwáju.
14
Èmi ń lépa láti dé òpin aré-ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kírísítì Jésù.
15
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fi hàn yín.
16
Kìkì pé, ibi tí a ti dé ná, ẹ jẹ́ kí a máa rìn ní ojú-ọ̀nà kan náà, kí a ni èrò kan náà.
17
Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ.
18
Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúùgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsinyìí, pé, ọ̀ta àgbélébùú Kírísítì ni wọ́n:
19
Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé.
20
Nítorí ìlú-ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ lọ́run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jésù Kírísítì Olúwa.
21
Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4