bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Philippians 4
Philippians 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
1
Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi.
2
Èmi ń bẹ̀ Éúódíà, mo sì ń bẹ Síńtíkè, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa.
3
Mo sì bẹ̀ ọ́ pẹ̀lú bí alájọrù àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìyìn rere, àti Kílẹ́mẹ́ńtì pẹ̀lú, àti àwọn olùbá-ṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.
4
Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀.
5
Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòòsí.
6
Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.
7
Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín máa nínú Kírísítì Jésù.
8
Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òótọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.
9
Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.
10
Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, níṣinṣinyìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fà mọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó.
11
Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀.
12
Mo mọ̀ bí a ti ṣe ń rẹ ara sílẹ̀, mo sì mọ̀ bí a ti ń di púpọ̀: ni ohunkóhun àti ní ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó àti láti wà ni àìjẹ, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní.
13
Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kírísítì ẹni ti ń fi agbára fún mi
14
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábàápín nínú ìpọ́njú mi.
15
Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Fílípì, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìn rere, nígbà tí mo kúrò ni Makedóníà, kò sí Ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábàápín ní ti gbígbà àti fífúnni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo.
16
Nítorí ní Tẹsalóníkà ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi.
17
Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín
18
Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀: mo sì kún nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Ẹ́páfíródítù tí a ti rán wá lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórún dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run.
19
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kírísítì Jésù.
20
Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín.
21
Ẹ kí olukùlùkù ènìyàn-mímọ́ nínú Kírísítì Jésù. Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín.
22
Gbogbo àwọn ènìyàn-mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Késárì.
23
Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
All chapters:
1
2
3
4