bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Ecclesiastes 5
Ecclesiastes 5
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 6 →
1
PA ẹsẹ rẹ mọ́ nigbati iwọ ba nlọ si ile Ọlọrun, ki iwọ ki o si mura ati gbọ́ jù ati ṣe irubọ aṣiwère: nitoriti nwọn kò rò pe nwọn nṣe ibi.
2
Máṣe fi ẹnu rẹ yara, ki o má si jẹ ki aiya rẹ ki o yara sọ ọ̀rọ niwaju Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun mbẹ li ọrun, iwọ si mbẹ li aiye: nitorina jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o mọ̀ ni ìwọn.
3
Nitoripe nipa ọ̀pọlọpọ iṣẹ ni alá ti iwá; bẹ̃ni nipa ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ li ã mọ̀ ohùn aṣiwère.
4
Nigbati iwọ ba jẹ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, máṣe duro pẹ lati san a: nitori kò ni inu-didun si aṣiwère: san eyi ti iwọ jẹjẹ́.
5
O san ki iwọ ki o má jẹ ẹjẹ́, jù ki iwọ ki o jẹ ẹjẹ́, ki o má san a.
6
Máṣe jẹ ki ẹnu rẹ ki o mu ara rẹ ṣẹ̀: ki iwọ ki o má si ṣe wi niwaju iranṣẹ Ọlọrun pe, èṣi li o ṣe: nitori kili Ọlọrun yio ṣe binu si ohùn rẹ, a si ba iṣẹ ọwọ rẹ jẹ?
7
Nitoripe bi ninu ọ̀pọlọpọ alá ni asan wà, bẹ̃ni ninu ọ̀pọlọpọ ọ̀rọ pẹlu: ṣugbọn iwọ bẹ̀ru Ọlọrun.
8
Bi iwọ ba ri inilara awọn olupọnju, ati ifi agbara yi idajọ ati otitọ pada ni igberiko, máṣe jẹ ki ẹnu ki o yà ọ si ọ̀ran na: nitoripe ẹniti o ga jù nṣọ ẹniti o ga, ati ẹni-giga-julọ wà lori wọn.
9
Pẹlupẹlu ère ilẹ ni fun gbogbo enia: a si nsìn ọba tikalarẹ pãpa lati inu oko wa.
10
Ẹniti o ba fẹ fadaka, fadaka kì yio tẹ́ ẹ lọrun; bẹ̃li ẹniti o fẹ ọrọ̀ kì yio tẹ́ ẹ lọrun: asan li eyi pẹlu.
11
Nigbati ẹrù ba npọ̀ si i, awọn ti o si njẹ ẹ a ma pọ̀ si i: ore ki tilẹ ni fun ẹniti o ni i bikoṣepe ki nwọn ki o ma fi oju wọn wò o?
12
Didùn ni orun oniṣẹ, iba jẹ onjẹ diẹ tabi pupọ: ṣugbọn itẹlọrun ọlọrọ̀ kì ijẹ, ki o sùn.
13
Ibi buburu kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, eyini ni pe, ọrọ̀ ti a pamọ́ fun ifarapa awọn ti o ni i.
14
Nitori ọrọ̀ wọnni a ṣegbe nipa iṣẹ buburu; bi o si bi ọmọkunrin kan, kò ni nkan lọwọ rẹ̀.
15
Bi o ti ti inu iya rẹ̀ jade wá, ihoho ni yio si tun pada lọ bi o ti wá, kì yio si mu nkan ninu lãla rẹ̀, ti iba mu lọ lọwọ rẹ̀.
16
Ibi buburu li eyi pẹlu, pe li ọ̀na gbogbo, bi o ti wá, bẹ̃ni yio si lọ: ère ki si ni fun ẹniti nṣe lãla fun afẹfẹ?
17
Li ọjọ rẹ̀ gbogbo pẹlu, o njẹun li òkunkun, o si ni ibinujẹ pupọ ati àrun ati irora rẹ̀.
18
Kiyesi eyi ti mo ri: o dara o si yẹ fun enia, ki o jẹ, ki o si mu, ki o si ma jẹ alafia ninu gbogbo lãla rẹ̀ ti o ṣe labẹ õrùn, ni iye ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, ti Ọlọrun fi fun u: nitori eyi ni ipin tirẹ̀.
19
Bi Ọlọrun ba fi ọrọ̀ fun ẹnikẹni, ti o si fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀: ati lati mu ipin rẹ̀, ati lati yọ̀ ninu lãla rẹ eyi; pẹlu ẹ̀bun Ọlọrun ni.
20
Nitoriti kì yio ranti ọjọ aiye rẹ̀ pọju; nitoriti Ọlọrun da a lohùn ninu ayọ̀ ọkàn rẹ̀.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12