bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Ecclesiastes 6
Ecclesiastes 6
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 7 →
1
IBI kan mbẹ ti mo ri labẹ õrùn, o si ṣọpọ lãrin awọn ọmọ enia.
2
Ẹniti Ọlọrun fi ọrọ̀, ọlà ati ọlá fun, ti kò si si nkan ti o si kù fun ọkàn rẹ̀ ninu ohun gbogbo ti o fẹ, ṣugbọn ti Ọlọrun kò fun u li agbara ati jẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn awọn ajeji enia li o njẹ ẹ: asan li eyi, àrun buburu si ni.
3
Bi ọkunrin kan bi ọgọrun ọmọ, ti o si wà li ọdun pupọ, tobẹ̃ ti ọjọ ọdun rẹ̀ pọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò si kún fun ohun didara, ati pẹlu ti a kò si sinkú rẹ̀; mo ni, ọmọ iṣẹnu san jù u lọ.
4
Nitoripe lasan li o wá, o si lọ li òkunkun, òkunkun li a o si fi bo orukọ rẹ̀ mọlẹ.
5
Pẹlupẹlu on kò ri õrùn kò mọ ohun kan: eyi ni isimi jù ekeji lọ.
6
Ani bi o tilẹ wà ni ẹgbẹrun ọdun lẹrin-meji, ṣugbọn kò ri rere: ibikanna ki gbogbo wọn ha nrè?
7
Gbogbo lãla enia ni fun ẹnu rẹ̀, ṣugbọn a kò ti itẹ adùn ọkàn rẹ̀ lọrun.
8
Nitoripe ère kili ọlọgbọ́n ni jù aṣiwère lọ? kini talaka ni ti o mọ̀ bi a ti rin niwaju awọn alãye?
9
Eyiti oju ri san jù irokakiri ifẹ lọ; asan li eyi pẹlu ati imulẹmofo.
10
Eyi ti o wà, a ti da orukọ rẹ̀ ri, a si ti mọ̀ ọ pe, enia ni: bẹ̃ni kò le ba ẹniti o lagbara jù u lọ jà.
11
Kiyesi i ohun pupọ li o wà ti nmu asan bi si i, ère kili enia ni?
12
Nitoripe tali o mọ̀ ohun ti o dara fun enia li aiye yi, ni iye ọjọ asan rẹ̀ ti nlọ bi ojiji? nitoripe tali o le sọ fun enia li ohun ti yio wà lẹhin rẹ̀ labẹ õrùn?
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12