bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Exodus 17
Exodus 17
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 18 →
1
GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si rìn lati ijù Sini lọ, ni ìrin wọn, gẹgẹ bi ofin OLUWA, nwọn si dó ni Refidimu: omi kò si si fun awọn enia na lati mu.
2
Nitorina li awọn enia na ṣe mbá Mose sọ̀, nwọn si wipe, Fun wa li omi ki a mu. Mose si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mbà mi sọ̀? ẽṣe ti ẹnyin fi ndán OLUWA wò?
3
Ongbẹ omi si ngbẹ awọn enia na nibẹ̀; awọn enia na si nkùn si Mose, nwọn si wipe, Ẽtiri ti iwọ fi mú wa goke lati Egipti wá, lati fi ongbẹ pa wa ati awọn ọmọ wa, ati ẹran wa?
4
Mose si kepè OLUWA, wipe, Kili emi o ṣe fun awọn enia yi? nwọn fẹrẹ̀ sọ mi li okuta.
5
OLUWA si wi fun Mose pe, Kọja lọ siwaju awọn enia na, ki o si mú ninu awọn àgbagba Israeli pẹlu rẹ, ki o si mú ọpá rẹ, ti o fi lù odò nì li ọwọ́ rẹ, ki o si ma lọ.
6
Kiyesi i, emi o duro niwaju rẹ nibẹ̀ lori okuta ni Horebu; iwọ o si lù okuta na, omi yio si jade ninu rẹ̀, ki awọn enia ki o le mu. Mose si ṣe bẹ̃ li oju awọn àgbagba Israeli.
7
O si sọ orukọ ibẹ̀ ni Massa, ati Meriba, nitori asọ̀ awọn ọmọ Israeli, ati nitoriti nwọn dan OLUWA wò pe, OLUWA ha mbẹ lãrin wa, tabi kò si?
8
Nigbana li Amaleki wá, o si bá Israeli jà ni Refidimu.
9
Mose si wi fun Joṣua pe, Yàn enia fun wa, ki o si jade lọ ibá Amaleki jà: li ọla li emi o duro lori oke ti emi ti ọpá Ọlọrun li ọwọ́ mi.
10
Joṣua si ṣe bi Mose ti wi fun u, o si bá Amaleki jà: ati Mose, Aaroni, on Huri lọ sori oke na.
11
O si ṣe, nigbati Mose ba gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, Israeli a bori: nigbati o ba si rẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ silẹ, Amaleki a bori.
12
Ṣugbọn ọwọ́ kún Mose; nwọn si mú okuta kan, nwọn si fi si abẹ rẹ̀, o si joko lé e; Aaroni ati Huri si mu u li ọwọ́ ró, ọkan li apa kini, ekeji li apa keji; ọwọ́ rẹ̀ si duro gan titi o fi di ìwọ-õrùn.
13
Joṣua si fi oju idà ṣẹgun Amaleki ati awọn enia rẹ̀ tútu
14
OLUWA si wi fun Mose pe, Kọ eyi sinu iwe fun iranti, ki o si kà a li eti Joṣua; nitoriti emi o pa iranti Amaleki run patapata kuro labẹ ọrun.
15
Mose si tẹ́ pẹpẹ kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni JEHOFA-nissi:
16
O si wipe, OLUWA ti bura: OLUWA yio bá Amaleki jà lati irandiran.
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40