bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Exodus 27
Exodus 27
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 28 →
1
IWỌ o si tẹ́ pẹpẹ igi ṣittimu kan, ìna rẹ̀ igbọnwọ marun, ati ìbú rẹ̀ igbọnwọ marun; ìwọn kan ni ìha mẹrẹrin: igbọnwọ mẹta si ni giga rẹ̀.
2
Iwọ o si ṣe iwo rẹ̀ si ori igun mẹrẹrin rẹ̀: iwo rẹ̀ yio si wà lara rẹ̀: iwọ o si fi idẹ bò o.
3
Iwọ o si ṣe tasà rẹ̀ lati ma gbà ẽru rẹ̀, ati ọkọ́ rẹ̀, ati awokòto rẹ̀ ati kọkọrọ ẹran rẹ̀, ati awo-iná rẹ̀ wọnni: gbogbo ohun-èlo rẹ̀ ni iwọ o fi idẹ ṣe.
4
Iwọ o si ṣe oju-àro idẹ fun u ni iṣẹ-àwọn; lara àwọn na ni ki iwọ ki o ṣe oruka mẹrin ni igun mẹrẹrin rẹ̀.
5
Iwọ o si fi si abẹ ayiká pẹpẹ na nisalẹ, ki àwọn na ki o le dé idaji pẹpẹ na.
6
Iwọ o si ṣe ọpá fun pẹpẹ na, ọpá igi ṣittimu, iwọ o si fi idẹ bò wọn.
7
A o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ oruka wọnni, ọpá wọnni yio si wà ni ìha mejeji pẹpẹ na, lati ma fi rù u.
8
Onihò ninu ni iwọ o fi apáko ṣe e: bi a ti fihàn ọ lori oke, bẹ̃ni ki nwọn ki o ṣe e.
9
Iwọ o si ṣe agbalá agọ́ na: ni ìha gusù lọwọ ọtún li aṣọ-tita agbalá ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ ti ọgọrun igbọnwọ ìna, yio wà ni ìha kan:
10
Ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ wọn, ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà.
11
Ati bẹ̃ gẹgẹ niti ìha ariwa ni gigùn aṣọ-tita wọnni yio jẹ́ ọgọrun igbọnwọ ni ìna wọn, ati ogún opó rẹ̀, ati ogún ihò-ìtẹbọ rẹ̀ ki o jẹ́ idẹ; ikọ́ opó wọnni ati ọpá isopọ̀ wọn ki o jẹ́ fadakà.
12
Ati niti ibú agbalá na, ni ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ yio wà: opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa.
13
Ati ibú agbalá na ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn yio jẹ́ ãdọta igbọnwọ.
14
Aṣọ-tita apakan ẹnu-ọ̀na na yio jẹ́ igbọnwọ mẹdogun: opó wọn mẹta, ihò-ìtẹbọ wọn mẹta.
15
Ati ni ìha keji ni aṣọ-tita igbọnwọ mẹdogun yio wà: opó wọn mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹta.
16
Ati fun ẹnu-ọ̀na agbalá na aṣọ-tita ogún igbọnwọ yio wà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe: opó wọn mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹrin.
17
Gbogbo opó ti o yi sarè na ká li a o si fi ọpá fadakà sopọ̀; ikọ́ wọn yio jẹ́ fadakà, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ.
18
Ìna agbalá na ki o jẹ́ ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ arãdọtọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ igbọnwọ marun, ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ.
19
Gbogbo ohun-èlo agọ́ na, ni gbogbo ìsin rẹ̀, ati gbogbo ekàn rẹ̀, ati gbogbo ekàn agbalá na ki o jẹ́ idẹ.
20
Iwọ o si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú oróro olifi daradara ti a gún fun ọ wá, fun imọlẹ, lati mu ki fitila ki o ma tàn nigbagbogbo.
21
Li agọ́ ajọ lẹhin ode aṣọ-ikele ti o wà niwaju ẹ̀rí na, Aaroni ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ ni yio tọju rẹ̀ lati alẹ titi di owurọ̀ niwaju OLUWA: yio si di ìlana lailai ni irandiran wọn lọdọ awọn ọmọ Israeli.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40