bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Hebrews 1
Hebrews 1
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 2 →
1
ỌLỌRUN, ẹni, ni igba pupọ̀ ati li onirũru ọna, ti o ti ipa awọn woli ba awọn baba sọ̀rọ nigbãni.
2
Ni ikẹhin ọjọ wọnyi o ti ipasẹ Ọmọ rẹ̀ ba wa sọ̀rọ, ẹniti o fi ṣe ajogun ohun gbogbo, nipasẹ ẹniti o dá awọn aiye pẹlu;
3
Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;
4
O si ti fi bẹ̃ di ẹniti o sàn ju awọn angẹli lọ, bi o ti jogun orukọ ti o ta tiwọn yọ.
5
Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi?
6
Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u.
7
Ati niti awọn angẹli, o wipe, Ẹniti o dá awọn angẹli rẹ̀ li ẹmí, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ li ọwọ́ iná.
8
Ṣugbọn niti Ọmọ li o wipe, Itẹ́ rẹ, Ọlọrun, lai ati lailai ni; ọpá alade ododo li ọpá alade ijọba rẹ.
9
Iwọ fẹ ododo, iwọ si korira ẹ̀ṣẹ; nitorina li Ọlọrun, ani Ọlọrun rẹ, ṣe fi oróro ayọ̀ yan ọ jù awọn ẹgbẹ rẹ lọ.
10
Ati Iwọ, Oluwa, li atetekọṣe li o ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; awọn ọrun si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ:
11
Nwọn ó ṣegbe; ṣugbọn iwọ ó wà sibẹ, gbogbo wọn ni yio si gbó bi ẹwu;
12
Ati bi aṣọ ni iwọ o si ká wọn, a o si pàrọ wọn: ṣugbọn bakanna ni iwọ, ọdún rẹ kì yio si pin.
13
Ṣugbọn ewo ninu awọn angẹli li o sọ nipa rẹ̀ ri pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ?
14
Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13