bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Hebrews 8
Hebrews 8
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 9 →
1
NJẸ pataki ninu ohun ti a nsọ li eyi: Awa ni irú Olori Alufa bẹ̃, ti o joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ ọla nla ninu awọn ọrun:
2
Iranṣẹ ibi mimọ́, ati ti agọ́ tõtọ, ti Oluwa pa, kì iṣe enia.
3
Nitori a fi olukuluku olori alufa jẹ lati mã mu ẹ̀bun wá ati lati mã rubọ: nitorina olori alufa yi pẹlu kò le ṣe aini ohun ti yio fi rubọ.
4
Nisisiyi ibaṣepe o mbẹ li aiye, on kì bá tilẹ jẹ alufa, nitori awọn ti nfi ẹbun rubọ gẹgẹ bi ofin mbẹ:
5
Awọn ẹniti njọsìn fun apẹrẹ ati ojiji awọn ohun ọrun, bi a ti kọ́ Mose lati ọdọ Ọlọrun wá nigbati o fẹ pa agọ́: nitori o wipe, kiyesi ki o ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi apẹrẹ ti a fihàn ọ lori òke.
6
Ṣugbọn nisisiyi o ti gbà iṣẹ iranṣẹ ti o ni ọlá jù, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti o dara jù ni iṣe, eyiti a fi ṣe ofin lori ileri ti o sàn jù bẹ̃ lọ.
7
Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju nì kò li àbuku, njẹ a kì ba ti wá àye fun ekeji.
8
Nitoriti o ri àbuku lara wọn, o wipe, Kiyesi i, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o bá ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.
9
Kì iṣe gẹgẹ bi majẹmu ti mo ti bá awọn baba wọn dá, li ọjọ na ti mo fà wọn lọwọ lati mu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti; nitoriti nwọn kò duro ninu majẹmu mi, emi kò si kà wọn si, ni Oluwa wi.
10
Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi:
11
Olukuluku kì yio si mã kọ́ ara ilu rẹ̀ ati olukuluku arakunrin rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo wọn ni yio mọ̀ mi, lati kekere de àgba.
12
Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.
13
Li eyi ti o wipe, Majẹmu titun, o ti sọ ti iṣaju di ti lailai. Ṣugbọn eyi ti o ndi ti lailai ti o si ngbó, o mura ati di asan.
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13