bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Job 28
Job 28
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 29 →
1
NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura.
2
Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá.
3
Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo.
4
Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia.
5
Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná.
6
Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura.
7
Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri.
8
Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí.
9
O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá.
10
O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo.
11
O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ.
12
Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye?
13
Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè.
14
Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi.
15
A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀.
16
A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri.
17
Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀.
18
A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ.
19
Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e.
20
Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye?
21
A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun.
22
Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀.
23
Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀,
24
Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun.
25
Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi.
26
Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá:
27
Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri.
28
Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42