bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Revelation 13
Revelation 13
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 14 →
1
O si duro lori iyanrìn okun, mo si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá, o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ̀ na ni orukọ ọrọ-odi.
2
Ẹranko ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀ si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla.
3
Mo si ri ọkan ninu awọn ori rẹ̀ bi ẹnipe a sá a pa, a si ti wo ọgbẹ aṣapa rẹ̀ na san, gbogbo aiye si fi iyanu tẹle ẹranko na.
4
Nwọn si foribalẹ fun dragoni na nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, Tali o dabi ẹranko yi? tali o si le ba a jagun?
5
A si fun u li ẹnu lati mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu mejilelogoji.
6
O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun.
7
A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ.
8
Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.
9
Bi ẹnikẹni ba li etí ki o gbọ́.
10
Bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a di ẹni igbèkun, igbèkun ni yio lọ: bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a fi idà pa ẹni, idà li a o si fi pa on na. Nihin ni sũru ati igbagbọ́ awọn enia mimọ́ gbé wà.
11
Mo si ri ẹranko miran goke lati inu ilẹ wá; o si ni iwo meji bi ọdọ-agutan, o si nsọ̀rọ bi dragoni.
12
O si nlò gbogbo agbara ẹranko ekini niwaju rẹ̀, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ foribalẹ fun ẹranko ekini ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ̀ san.
13
O si nṣe ohun iyanu nla, ani ti o fi nmu iná sọkalẹ lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia.
14
O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè.
15
A si fi fun u lati fi ẹmí fun aworan ẹranko na ki o mã sọ̀rọ, ki o si mu ki a pa gbogbo awọn ti kò foribalẹ fun aworan ẹranko na.
16
O si mu gbogbo wọn, ati kekere ati nla, ọlọrọ̀ ati talakà, omnira ati ẹrú, ki a fi àmi kan fun wọn li ọwọ́ ọtún wọn, tabi ni iwaju wọn:
17
Ati ki ẹnikẹni má le rà tabi ki o tà, bikoṣe ẹniti o bá ni ami orukọ ẹranko na, tabi iye orukọ rẹ̀.
18
Nihin ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹniti o ba ni oye, ki o ṣiro iye ti mbẹ lara ẹranko na: nitori iye enia ni; iye rẹ̀ na si jẹ ọ̀talelẹgbẹta o le mẹfa.
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22