bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Revelation 9
Revelation 9
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 10 →
1
ANGẸLI karun si fun, mo si ri irawọ kan bọ́ si ilẹ lati ọrun wá: a si fi iṣika iho ọgbun fun u.
2
O si ṣí iho ọgbun na; ẹ̃fin si ru jade lati inu iho na wá, bi ẹ̃fin ileru nla; õrùn ati oju sanma si ṣõkun nitori ẹ̃fin iho na.
3
Ẽṣú si jade ti inu ẹ̃fin na wá sori ilẹ: a si fi agbara fun wọn bi akẽkẽ ilẹ ti li agbara.
4
A si sọ fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe pa koriko ilẹ lara, tabi ohun tutù kan, tabi igikigi kan; bikoṣe awọn enia ti kò ni èdidi Ọlọrun ni iwaju wọn.
5
A si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe pa wọn, ṣugbọn ki a dá wọn li oró li oṣù marun: oró wọn si dabi oró akẽkẽ, nigbati o ba ta enia.
6
Li ọjọ wọnni li awọn enia yio si mã wá ikú, nwọn kì yio si ri i; nwọn o si fẹ lati kú, ikú yio si sá kuro lọdọ wọn.
7
Iré awọn ẽṣú na si dabi awọn ẹṣin ti a mura silẹ fun ogun; ati li ori wọn ni bi ẹnipe awọn ade ti o dabi wura wà, oju wọn si dabi oju enia;
8
Nwọn si ni irun bi irun obinrin, ehin wọn si dabi ti kiniun.
9
Nwọn si ni awo ìgbàiya, bi awo ìgbàiya irin; iró iyẹ́ wọn si dabi iró kẹkẹ́ ẹṣin pupọ̀ ti nsúré lọ si ogun.
10
Nwọn si ni ìru ati oró bi ti akẽkẽ, ati ni ìru wọn ni agbara wọn wà lati pa enia lara fun oṣù marun.
11
Nwọn ni angẹli ọgbun na bi ọba lori wọn, orukọ rẹ̀ li ede Heberu ni Abaddoni, ati li ède Griki orukọ rẹ̀ amã jẹ Apollioni.
12
Egbé kan kọja; kiyesi i, egbé meji mbọ̀ sibẹ lẹhin eyi.
13
Angẹli kẹfa si fun, mo si gbọ́ ohùn kan lati ibi iwo mẹrin pẹpẹ wura wá, ti mbẹ niwaju Ọlọrun,
14
Nwi fun angẹli kẹfa na ti o ni ipè na pe, Tú awọn angẹli mẹrin nì silẹ ti a dè lẹba odò nla Eufrate.
15
A si tú awọn angẹli mẹrin na silẹ, ti a ti pese tẹlẹ fun wakati na, ati ọjọ na, ati oṣù na, ati ọdun na, lati pa idamẹta enia.
16
Iye ogun awọn ẹlẹṣin si jẹ ãdọta ọkẹ́ lọna igba: mo si gbọ́ iye wọn.
17
Bayi ni mo si ri awọn ẹṣin na li ojuran, ati awọn ti o gùn wọn; nwọn ni awo ìgbaiya iná, ati ti jakinti, ati ti imí ọjọ: ori awọn ẹṣin na si dabi ori awọn kiniun; ati lati ẹnu wọn ni iná, ati ẹ̃fin, ati imí ọjọ ti njade.
18
Nipa iyọnu mẹta wọnyi li a ti pa idamẹta enia, nipa iná, ati nipa, ẹ̃fin, ati nipa imí ọjọ ti o nti ẹnu wọn jade.
19
Nitoripe agbara awọn ẹṣin na mbẹ li ẹnu wọn ati ni iru wọn: nitoripe ìru wọn dabi ejò, nwọn si ni ori, awọn wọnyi ni nwọn si fi npa-ni-lara.
20
Ṣugbọn awọn enia iyokù, ti a kò si ti ipa iyọnu wọnyi pa, kò si ronupiwada iṣẹ́ ọwọ́ wọn, ki nwọn ki o máṣe sìn awọn ẹmi èṣu, ati ere wura, ati ti fadaka, ati ti idẹ, ati ti okuta, ati ti igi mọ́, awọn ti kò le riran, tabi ki nwọn gbọran, tabi ki nwọn rìn:
21
Bẹ̃ni nwọn kò ronupiwada enia pipa wọn, tabi oṣó wọn, tabi àgbere wọn, tabi olè wọn.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
Recommended Reading
Commentary
Revelation Commentaries
→
Devotional
Revelation Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ) Study Bible
→