bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Zechariah 2
Zechariah 2
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 3 →
1
MO si tun gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti on ti okùn-iwọ̀n lọwọ rẹ̀.
2
Mo si wipe, Nibo ni iwọ nlọ? o si wi fun mi pe, Lati wọ̀n Jerusalemu, lati ri iye ibú rẹ̀, ati iye gigùn rẹ̀.
3
Si kiyesi i, angeli ti o mba mi sọ̀rọ jade lọ, angeli miran si jade lọ ipade rẹ̀.
4
O si wi fun u pe, Sare, sọ fun ọdọmọkunrin yi wipe, a o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọ enia ati ohun-ọsìn inu rẹ̀:
5
Oluwa wipe, Emi o si jẹ odi iná fun u yika, emi o si jẹ ogo lãrin rẹ̀.
6
Ã! ã! sá kuro ni ilẹ ariwa, ni Oluwa wi; nitoripe bi afẹfẹ mẹrin ọrun ni mo tu nyin kakiri, ni Oluwa wi.
7
Sioni, gba ara rẹ là, iwọ ti o mba ọmọbinrin Babiloni gbe.
8
Nitori bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; lẹhìn ogo li o ti rán mi si awọn orilẹ-ède ti nkó nyin: nitori ẹniti o tọ́ nyin, o tọ́ ọmọ oju rẹ̀.
9
Nitori kiyesi i, emi o gbọ̀n ọwọ mi si ori wọn, nwọn o si jẹ ikogun fun iranṣẹ wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi.
10
Kọrin ki o si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: sa wò o, mo de, emi o si gbe ãrin rẹ, ni Oluwa wi.
11
Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio dapọ̀ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si di enia mi; emi o si gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ.
12
Oluwa o si jogún Juda iní rẹ̀, nilẹ̀ mimọ́, yio si tun yàn Jerusalemu.
13
Ẹ dakẹ, gbogbo ẹran-ara niwaju Oluwa: nitori a ji i lati ibùgbe mimọ́ rẹ̀ wá.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14