bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Zechariah 7
Zechariah 7
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 8 →
1
O si ṣe li ọdun kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah wá ni ijọ kẹrin oṣù kẹsan, Kislefi;
2
Nigbati nwọn rán Ṣereṣeri ati Regemmeleki, ati awọn enia wọn si ile Ọlọrun lati wá oju rere Oluwa.
3
Ati lati bá awọn alufa ti o wà ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati awọn woli sọ̀rọ, wipe, Ki emi ha sọkun li oṣù karun, ki emi ya ara mi sọtọ, bi mo ti nṣe lati ọdun melo wonyi wá?
4
Nigbana li ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun tọ̀ mi wá wipe,
5
Sọ fun gbogbo awọn enia ilẹ na, ati fun awọn alufa, wipe, Nigbati ẹnyin gbawẹ̀ ti ẹ si ṣọ̀fọ li oṣù karun ati keje, ani fun ãdọrin ọdun wọnni, ẹnyin ha gbawẹ̀ si mi rara, ani si emi?
6
Nigbati ẹ si jẹ, ati nigbati ẹ mu, fun ara nyin ki ẹnyin ha jẹ, ati fun ara nyin ki ẹnyin ha mu?
7
Wọnyi kì ọ̀rọ ti Oluwa ti kigbe lati ọdọ awọn woli iṣãju wá, nigbati a ngbe Jerusalemu, ti o si wà li alafia, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ti o yi i ka kiri, nigbati a ngbe gusù ati pẹtẹlẹ?
8
Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Sekariah wá, wipe,
9
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Dá idajọ otitọ, ki ẹ si ṣe ãnu ati iyọ́nu olukuluku si arakunrin rẹ̀.
10
Má si ṣe ni opó lara, tabi alainibaba, alejo, tabi talakà; ki ẹnikẹni ninu nyin ki o máṣe gbèro ibi li ọkàn si arakunrin rẹ̀.
11
Ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gbọ́, nwọn si gùn ejika, nwọn si di eti wọn, ki nwọn ki o má bà gbọ́.
12
Ani nwọn ṣe aiya wọn bi okuta adamanti, ki nwọn ki o má ba gbọ́ ofin, ati ọ̀rọ ti Ọluwa awọn ọmọ-ogun ti fi ẹmi rẹ̀ rán nipa ọwọ awọn woli iṣãju wá: ibinu nla si de lati ọdọ Ọluwa awọn ọmọ-ogun wá.
13
O si ṣe, gẹgẹ bi o ti kigbe, ti nwọn kò si fẹ igbọ́, bẹ̃ni nwọn kigbe, ti emi kò si fẹ igbọ́, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
14
Mo si fi ãja tú wọn ka si gbogbo orilẹ-ède ti nwọn kò mọ̀. Ilẹ na si dahoro lẹhin wọn, ti ẹnikẹni kò là a kọja tabi ki o pada bọ̀: nwọn si sọ ilẹ ãyò na dahoro.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14