bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
1 Samuel 16
1 Samuel 16
Yoruba 2010
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
1
OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Ìgbà wo ni o fẹ́ káàánú lórí Saulu dà? Ṣebí o mọ̀ pé mo ti kọ̀ ọ́ lọ́ba lórí Israẹli. Rọ òróró kún inú ìwo rẹ kí o lọ sọ́dọ̀ Jese ará Bẹtilẹhẹmu, mo ti yan ọba kan fún ara mi ninu àwọn ọmọ rẹ̀.”
2
Samuẹli dáhùn pé, “Báwo ni n óo ṣe lọ? Bí Saulu bá gbọ́, pípa ni yóo pa mí.” OLUWA dá a lóhùn pé, “Mú ọ̀dọ́ mààlúù kan lọ́wọ́, kí o wí pé o wá rúbọ sí OLUWA ni.
3
Pe Jese wá sí ibi ẹbọ náà, n óo sì sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ. N óo dárúkọ ẹnìkan fún ọ, ẹni náà ni kí o fi jọba.”
4
Samuẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún un, ó lọ sí Bẹtilẹhẹmu. Gbígbọ̀n ni àwọn àgbààgbà ìlú bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n bí wọ́n ti ń lọ pàdé rẹ̀. Wọ́n bi í pé, “Ṣé alaafia ni?”
5
Samuẹli dáhùn pé, “Alaafia ni. Ẹbọ ni mo wá rú sí OLUWA. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ bá mi lọ síbi ìrúbọ náà.” Ó ya Jese ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, ó sì pè wọ́n síbi ìrúbọ náà.
6
Nígbà tí wọ́n dé, ó wo Eliabu, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú ẹni tí OLUWA yàn nìyí.”
7
Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.”
8
Lẹ́yìn náà, Jese sọ fún Abinadabu pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli wí pé, “OLUWA kò yan eléyìí.”
9
Lẹ́yìn náà Jese sọ fún Ṣama pé kí ó kọjá níwájú Samuẹli. Samuẹli tún ní, “OLUWA kò yan eléyìí náà.”
10
Jese mú kí àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeje kọjá níwájú Samuẹli. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, OLUWA kò yan ọ̀kankan ninu wọn.
11
Samuẹli bá bèèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé gbogbo àwọn ọmọ rẹ ọkunrin nìyí?” Jese dáhùn, ó ní, “Ó ku èyí tí ó kéré jù, ṣugbọn ó ń tọ́jú agbo ẹran.” Samuẹli bá wí fún Jese, pé, “Ranṣẹ lọ pè é wá, nítorí pé a kò ní jókòó títí yóo fi dé.”
12
Jese ranṣẹ lọ mú un wá. Ọmọ náà jẹ́ ọmọ pupa, ojú rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà. OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Dìde, kí o ta òróró sí i lórí nítorí pé òun ni mo yàn.”
13
Nígbà náà ni Samuẹli mú ìwo tí òróró wà ninu rẹ̀, ó ta òróró náà sí i lórí láàrin àwọn arakunrin rẹ̀, Ẹ̀mí OLUWA sì bà lé Dafidi láti ọjọ́ náà lọ. Samuẹli bá gbéra, ó pada sí Rama.
14
Ẹ̀mí OLUWA kúrò lára Saulu, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA sì ń dà á láàmú.
15
Àwọn iranṣẹ Saulu wí fún un pé, “Wò ó! Ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ OLUWA ń dà ọ́ láàmú;
16
fún àwa iranṣẹ rẹ tí a wà níwájú rẹ láṣẹ láti wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára. Ìgbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bá bà lé ọ, yóo máa fi hapu kọrin, ara rẹ yóo sì balẹ̀.”
17
Saulu bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n wá ọkunrin kan tí ó mọ hapu ta dáradára, kí wọ́n sì mú un wá siwaju òun.
18
Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin náà dáhùn pé, “Wò ó! Mo ti rí ọmọ Jese ará Bẹtilẹhẹmu tí ó mọ hapu ta dáradára. Ó jẹ́ alágbára ati akọni lójú ogun, ó ní ọ̀rọ̀ rere lẹ́nu, ó lẹ́wà, OLUWA sì wà pẹlu rẹ̀.”
19
Saulu bá ranṣẹ sí Jese pé kí ó fi Dafidi, ọmọ rẹ̀ tí ń tọ́jú agbo ẹran ranṣẹ sí òun.
20
Jese di ẹrù burẹdi ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ati waini tí wọ́n rọ sinu ìgò aláwọ pẹlu ọmọ ewúrẹ́ kan, ó kó wọn rán Dafidi sí Saulu.
21
Dafidi wá sọ́dọ̀ Saulu, ó sì ń bá a ṣiṣẹ́. Saulu fẹ́ràn rẹ̀ gidigidi, ó sì di ẹni tí ń ru ihamọra Saulu.
22
Saulu ranṣẹ sí Jese, ó ní, “Jẹ́ kí Dafidi máa bá mi ṣiṣẹ́ nítorí ó ti bá ojurere mi pàdé.”
23
Nígbàkúùgbà tí ẹ̀mí burúkú bá ti ọ̀dọ̀ OLUWA wá sórí Saulu, Dafidi a máa ta hapu fún un, ara Saulu á balẹ̀, ẹ̀mí burúkú náà a sì fi í sílẹ̀.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31