bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
1 Samuel 21
1 Samuel 21
Yoruba 2010
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 22 →
1
Dafidi lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki alufaa, ní Nobu. Ahimeleki sì jáde pẹlu ìbẹ̀rù láti pàdé rẹ̀, ó sì bi í pé, “Ṣé kò sí nǹkan tí ìwọ nìkan fi dá wá, tí kò sí ẹnikẹ́ni pẹlu rẹ?”
2
Ó dáhùn pé, “Ọba ni ó rán mi ní iṣẹ́ pataki kan, ó sì ti sọ fún mi pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ tí òun rán mi. Mo sì ti sọ fún àwọn iranṣẹ mi pé kí wọ́n pàdé mi ní ibìkan.
3
Kí ni ẹ ní lọ́wọ́? Fún mi ní ìṣù burẹdi marun-un tabi ohunkohun tí o bá ní.”
4
Alufaa náà sì dáhùn pé, “N kò ní burẹdi lásán, àfi èyí tí ó jẹ́ mímọ́. Mo lè fún ọ tí ó bá dá ọ lójú pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pa ara wọn mọ́, tí wọn kò sì bá obinrin lòpọ̀.”
5
Dafidi dáhùn pé, “Àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi a máa pa ara wọn mọ́ nígbà tí a bá ń lọ fún iṣẹ́ tí kò ṣe pataki, kí á tó wá sọ ti iṣẹ́ yìí, tí ó jẹ́ iṣẹ́ pataki?”
6
Alufaa kó àwọn burẹdi mímọ́ náà fún Dafidi, nítorí pé kò sí òmíràn níbẹ̀, àfi burẹdi ìfihàn tí wọ́n kó kúrò níwájú OLUWA láti fi òmíràn rọ́pò rẹ̀.
7
Doegi, olórí darandaran Saulu, ará Edomu wà níbẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ó ń jọ́sìn níwájú OLUWA.
8
Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki pé, “Ǹjẹ́ o ní ọ̀kọ̀ tabi idà kí o fún mi? Ìkánjú tí mo fi kúrò nílé kò jẹ́ kí n ranti mú idà tabi ohun ìjà kankan lọ́wọ́.”
9
Ahimeleki sì dáhùn pé, “Idà Goliati ará Filistia tí o pa ní àfonífojì Ela nìkan ni ó wà ní ibí. A fi aṣọ kan wé e sí ẹ̀yìn efodu. Bí o bá fẹ́, o lè mú un. Kò sì sí òmíràn níbí lẹ́yìn rẹ̀.” Dafidi dáhùn pé, “Kò sí idà tí ó dàbí rẹ̀, mú un fún mi.”
10
Dafidi sá fún Saulu ní ọjọ́ náà. Ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi, ọba Gati.
11
Àwọn iranṣẹ Akiṣi sì sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ Dafidi, ọba ilẹ̀ rẹ̀ kọ́ nìyí, tí àwọn obinrin ń kọrin nípa rẹ̀ pé: ‘Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”
12
Dafidi fi àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi sọ́kàn ó ṣe bí ẹni pé kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ṣugbọn ó bẹ̀rù Akiṣi, ọba Gati gidigidi.
13
Ó yí ìṣe rẹ̀ pada níwájú wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bíi wèrè. Ó ń fi ọwọ́ ha ìlẹ̀kùn ojú ọ̀nà ààfin, ó sì ń wa itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀.
14
Akiṣi bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ kò rí i pé aṣiwèrè ni ọkunrin yìí ni, kí ló dé tí ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi?
15
Ṣé n kò ní aṣiwèrè níhìn-ín ni, tí ẹ fi mú un wá siwaju mi kí ó wá ṣe wèrè rẹ̀? Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí ni ó yẹ kí ó wá sinu ilé mi?”
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31