bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
1 Samuel 5
1 Samuel 5
Yoruba 2010
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 6 →
1
Lẹ́yìn tí àwọn ará Filistia gba àpótí Ọlọrun lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n gbé e láti Ebeneseri lọ sí Aṣidodu.
2
Wọ́n gbé e lọ sí ilé Dagoni, oriṣa wọn; wọ́n sì gbé e kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ère oriṣa náà.
3
Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, àwọn ará ìlú Aṣidodu rí i pé ère Dagoni ti ṣubú lulẹ̀. Wọ́n bá a tí ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA. Wọ́n bá gbé e dìde, wọ́n gbé e pada sí ààyè rẹ̀.
4
Nígbà tí ó tún di òwúrọ̀ kutukutu wọ́n tún bá a tí ère náà tún ti ṣubú tí ó tún ti dojú bolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA, ati pé orí ati ọwọ́ rẹ̀ mejeeji ti gé kúrò, wọ́n wà nílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.
5
Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé títí di òní olónìí, àwọn babalóòṣà oriṣa Dagoni ati gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń bọ ọ́ kò jẹ́ tẹ ẹnu ọ̀nà ilé oriṣa Dagoni tí ó wà ní ìlú Aṣidodu, dídá ni wọ́n máa ń dá a kọjá.
6
OLUWA jẹ àwọn ará ìlú Aṣidodu níyà gidigidi, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ìyà tí ó fi jẹ wọ́n, ati àwọn tí wọn ń gbé agbègbè wọn ni pé gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún.
7
Nígbà tí àwọn ará Aṣidodu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun Israẹli ni ó ń jẹ àwa ati Dagoni, oriṣa wa níyà. A kò lè jẹ́ kí àpótí Ọlọrun Israẹli yìí wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín mọ́ rárá.”
8
Wọ́n bá ranṣẹ lọ pe àwọn ọba Filistini jọ, wọ́n sì bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí Ọlọrun Israẹli yìí?” Wọ́n dáhùn pé kí wọ́n gbé e lọ sí Gati; wọ́n bá gbé e lọ sibẹ.
9
Ṣugbọn nígbà tí àpótí Ọlọrun náà dé Gati, OLUWA jẹ ìlú náà níyà, ó mú kí gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún ati àgbà ati èwe wọn, ó sì mú ìpayà bá gbogbo wọn.
10
Wọ́n tún gbé àpótí Ọlọrun náà ranṣẹ sí ìlú Filistini mìíràn, tí wọn ń pè ní Ekironi. Ṣugbọn bí wọ́n ti gbé e dé Ekironi ni àwọn ará ìlú fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí Ọlọrun Israẹli dé síhìn-ín, láti pa gbogbo wa run.”
11
Wọ́n bá ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ gbé àpótí Ọlọrun Israẹli pada sí ibi tí ẹ ti gbé e wá, kí ó má baà pa àwa ati ìdílé wá run.” Ìpayà ńlá ti bá gbogbo ìlú nítorí OLUWA ń jẹ wọ́n níyà gidigidi.
12
Ara gbogbo àwọn tí kò kú ninu wọn kún fún kókó ọlọ́yún. Ariwo àwọn eniyan náà sì pọ̀ pupọ.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31