bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Samuel 1
2 Samuel 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 2 →
1
Lẹ́yìn ikú Ṣọ́ọ̀lù, Dáfídì ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Ámálékì bọ̀, ó sì dúró ní Síkílágì ní ọjọ́ méjì.
2
Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Ṣọ́ọ̀lù, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dáfídì, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.
3
Dáfídì sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?” “Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”
4
Dáfídì béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jónátanì sì kú pẹ̀lú.”
5
Nígbà náà, ní Dáfídì sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jónátanì ti kú.”
6
“Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, mo wà ní orí òkè Gílíbóà níbẹ̀ ni Ṣọ́ọ̀lù fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.
7
Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, kí ni mo lè ṣe?
8
“Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’ “Mo dáhùn pé, ‘Ará a Ámálékì,’
9
“Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láàyè.’
10
“Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún OLÚWA mi.”
11
Nígbà náà ni, Dáfídì àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya.
12
Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sunkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Ṣọ́ọ̀lù àti ọmọ rẹ̀ Jónátanì àti fún àwọn ọmọ ogun OLÚWA, àti fún àwọn ilé Ísírẹ́lì, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà.
13
Dáfídì sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?” O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Ámálékì.”
14
Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró OLÚWA?”
15
Nígbà náà Dáfídì pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú.
16
Nítorí Dáfídì wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé ‘Mo pa ẹni àmì òróró OLÚWA.’ ”
17
Dáfídì sì fi orin arò yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Ṣọ́ọ̀lù àti lórí Jónátanì ọmọ rẹ̀,
18
Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Júdà ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jáṣárì):
19
“Ogo rẹ, Ísírẹ́lì ni a pa ní òkè gíga rẹ. Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!
20
“Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gátì, ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Áṣíkélónì, kí àwọn ọmọbìnrin Fílístínì má bá à yọ̀, kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má baà dunnú.
21
“Ẹ̀yin òkè Gílíbóà, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni aṣà alágbára ti ṣègbé, aṣà Ṣọ́ọ̀lù, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.
22
Ọrun Jónátánì kì í padà bẹ́ẹ̀ ni idà Ṣọ́ọ̀lù kì í padà lásán, láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, àti ẹran àwọn alágbára.
23
“Ṣọ́ọ̀lù àti Jónátanì— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n. Wọ́n yára ju àṣá lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.
24
“Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì, ẹ sunkún lórí Ṣọ́ọ̀lù, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fí wúrà sí ara aṣọ yín.
25
“Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun! Jónátánì, ìwọ tí a pa ní òkè gíga.
26
Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jónátanì arákùnrin mi; ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi. Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu, ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ.
27
“Wò ó bí alágbára ti ṣubú! Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24